TESCOM kede awọn to yege ninu idanwo igbanisiṣẹ olukọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

Monday, April 7, 2025

demo-image

TESCOM kede awọn to yege ninu idanwo igbanisiṣẹ olukọ ni Kwara


Ileeṣẹ to n ri sọrọ eto igbaniwọle siṣẹ olukọ, ẹka tipinlẹ Kwara, Kwara State Teaching Service Commission (TESCOM), ti sọ pe awọn oluforukọsilẹ ti ko din ni ẹgbẹrun kan ati ọgọsan (1,800) ni wọn yege fun iṣẹ naa.

Ninu atẹjade ti Sam Onile to jẹ akọwe iroyin fun TESCOM fi sita lọjọ Aiku to kọja, o ni lẹyin ayẹwo ati idanwo loriṣiriṣi ni awọn to le gbe ikede naa sita.

O sọ pe awọn ti wọn mu yii lo ti la idanwo, ayẹwo lori ayelujara ati ẹrọ kọmputa pẹlu ifọrọwanilẹnuwo to waye laarin oṣu bii mẹta kọja.

O sọ pe awọn olukọ naa ni wọn yoo pin s'awọn ile ẹkọ girama kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa lati bẹrẹ iṣẹ, ni ibamu pẹlu ilana ileeṣẹ naa.

Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe ki awọn to farahan fun ifọrọwanilẹnuwo lọ soju opo ileeṣẹ naa lati mọ boya wọn yege, ati pe lẹyin naa ni wọn yoo tun lọ fun ayẹwo ilera lati mọ awọn to n mu egboogi oloro.

"Ayẹwo lilo egboogi oloro naa ni ajọ NDLEA yoo ṣe, ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori aṣilo oogun, Ọnarebu Mukail Olamilekan Aileru yoo ṣagbatẹru rẹ," atẹjade ọhun ṣalaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *