Ilu Badagry yoo mi titi lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to n bọ yii, ọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun 2025.
Ọjọ naa ni Ijọ 'Oloriṣa Parapọ Agbaaye' fẹẹ fi gbajugbaja oloṣelu ati oludije sipo gomina nipinlẹ Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Gbadebo Rhodes-Vivour joye Ọbalẹfun (Peace Ambassador) ijọ naa.
Gbọngan ayẹyẹ ti ile itura Ayapot to wa ni Ado-Odo, niluu Badagry layẹyẹ, naa yoo ti waye.
Nitori ipa nla ti ọkunrin oloṣelu naa ti ko fun idagbasoke ati ilọsiwaju awọn eeyan lo jẹ ki wọn fẹẹ foye nla ọhun da a lọla.
Awọn eeyan pataki lawujọ ni wọn n reti nibi ayẹyẹ iwuye naa.
No comments:
Post a Comment