KWASUED bẹrẹ eto igbaniwọle si ẹka ikẹkọọ BSc tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 5, 2025

demo-image

KWASUED bẹrẹ eto igbaniwọle si ẹka ikẹkọọ BSc tuntun


Ile ẹkọ fasiti KWASUED, iyẹn Kwara State University of Education to wa niluu Ilorin ipinlẹ Kwara ti kede eto igbaniwọle s'awọn ẹka ikẹkọọ tuntun fun iwe ẹri BSc.

Ninu atẹjade ti alakoso eto igbaniwọle ni fasiti naa, Mohammed Jimada Jibril fi sita, o sọ pe asiko naa ree fawọn akẹkọọ ti wọn n foju sọna lati kẹkọọgboye, paapaa lawọn ilana eto ẹkọ tuntun lati gba fọọmu.

Jibril sọ pe awọn akọṣẹmọṣẹ olukọ ati Ọjọgbọn ni wọn wa ni fasiti naa, ti wọn n kọ awọn akẹkọọ ni ilana eto ẹkọ to ye kooro, eyi to ba ti agbaye mu.

O ni awọn akọṣẹmọṣẹ olufọkansin ni fasiti naa n gbe dide, ti wọn yoo si tayọ ni oniruuru ibi ti wọn ba ti ba ara wọn lagbaye.

"KWASUED jẹ fasiti ti wọn da silẹ lara-ọtọ nipa gbigbe awọn olukọni to n lo ilana eto ẹkọ igbalode dide, awọn to n gbe ironujinlẹ dide, agbekalẹ onitẹsiwaju, ati kikẹkọọ ni yara ikẹkọọ ti wọn ba ti ba ara wọn," Jibril sọ ninu atẹjade ọhun.

O tẹsiwaju pe ajọ National Universities Commission (NUC) buwọ lu awọn gbogbo ilana eto ẹkọ ati ikẹkọọ wọn, ti wọn si ni awọn ilana ikẹkọọ igbalode to yọranti, eyi to n jẹ ki awọn akẹkọọ maa ṣe aṣeyọri to peye lagboole eto ẹkọ.

Awọn ilana eto ẹkọ ati ẹka ikẹkọọ naa ree:

B.A.Ed. Creative Arts Education

B.A.Ed. English Language

B.A.Ed. History

B.A.Ed. Yoruba

B.Ed. Educational Management

B.Ed. Educational Technology

B.Ed. Entrepreneurship

B.Ed. Guidance and Counseling

B.Ed. Sustainable Development

B.Sc.Ed. Accounting

B.Sc.Ed. Agriculture

B.Sc.Ed. Biology Education

B.Sc.Ed. Business Education

B.Sc.Ed. Chemistry Education

B.Sc.Ed. Computer Science Education

B.Sc.Ed. Economics

B.Sc.Ed. Home Economics

B.Sc.Ed. Mathematics

B.Sc.Ed. Physics

B.Tech.Ed Electronics and Electrical

Siwaju sii ni Jibril jẹ ko di mimọ pe awọn akẹkọọ to ṣe idanwo UTME, ṣugbọn ti wọn ko mu wọn fun fasiti akọkọ le forukọsilẹ fun ayipads fasiti lori ikanni ayelujara ti JAMB.

Fun alaye lẹkunrẹrẹ, ẹ le kan si www.kwasued.edu.ng tabi ki ẹ pe awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyi; 08035725654, 08102783716, 08066001312.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *