Gomina tipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori iyansipo Onimọ-ẹrọ Bashir Bayo Ojulari, gẹgẹ bi alakoso agba fun ileeṣẹ to n ṣabojuto epo rọbii lorileede Naijiria, NNPC.
AbdulRazaq ṣapejuwe iyansipo naa gẹgẹ bi oriire nla fun ipinlẹ Kwara ati awọnn araalu naa, leyi to waye lẹyin ọjọ diẹ ti wọn yan Sẹnetọ Ibrahim Yahya Oloriẹgbẹ gẹgẹ bi alaga ajọ National Health Insurance Authority (NHIA).
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita, Gomina AbdulRazaq tun ki Onimọ-ẹrọ Ojulari ku oriire aṣeyọri nla naa, to si loun nigbagbọ pe yoo ṣe ipo naa daadaa.
No comments:
Post a Comment