Ẹgbẹ DIYO gbe oriyin fun Aarẹ Tinubu lori iyansipo Sẹnetọ Oloriẹgbẹ gẹgẹ bi alaga ajọ NHIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 3, 2025

Ẹgbẹ DIYO gbe oriyin fun Aarẹ Tinubu lori iyansipo Sẹnetọ Oloriẹgbẹ gẹgẹ bi alaga ajọ NHIA


Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni DIYO Support Group ti dupẹ gidigidi lọwọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori bo ṣe yan Sẹnetọ Ibrahim Yahaya Oloriegbe gẹgẹ bi alaga igbimọ iṣakoso ajọ eleto ilera ti wọn pe ni National Health Insurance Authority (NHIA).

Wọn tun gbe oṣuba kare fun Gomina ipinlẹ Kwara, Mallam AbdulRahman AbdulRazaq, lori bo ṣe dide si ọrọ iyansipo naa, to si jẹ ko bọ si ọmọ ipinlẹ naa lọwọ.
 
Nibi eto ipade awọn akọroyin to waye niluu Ilorin l'Ọjọru, ọsẹ yii, agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Onimọ-ẹrọ Jimoh Ajani, ṣapejuwe iyansipo ọhun gẹgẹ bi ipa rere to jọju, ti awọn si mọ pataki rẹ pupọ.
 
Ajani sọ pe inu awọn dun lori iyansipo Sẹnetọ Oloriẹgbẹ, ẹni to ti ko ipa ribiribi ninu idagbasoke ipinlẹ naa, paapaa lorileede Naijiria, lẹka eto ilera.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI