Oluyẹmi, alakoso ile-itura ku loju oorun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 24, 2025

Oluyẹmi, alakoso ile-itura ku loju oorun l'Abẹokuta


Adura ti ọpọ eeyan maa n gba bi wọn ba fẹ lọọ sun lalaalẹ wi pe ‘Ọlọrun ma jẹ ka toju oorun de oju iku’, ni wọn sọ pe ko gba fun alakoso otẹẹli kan to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọsẹ to kọja yii, pẹlu bi wọn sọ pe oju oorun lo wa ti ọlọjọ fi de.

Adedokun Oluyẹmi ni wọn pe orukọ ọkunrin naa, ẹni ti wọn loun ni alabojuto otẹẹli Solution One to wa lagbegbe Ago-Oko, ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, opin ọsẹ to kọja yii niṣẹlẹ naa waye, to si n jẹ kayeefi fun awọn ara agbegbe naa, paapaa awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ nile itura naa.

‘Ko le jẹ bẹẹ’, ‘irọ ni’, ‘a ṣi jọ dọwẹkẹ titi lalẹ ana ni’, wọnyi ati awọn ọrọ iyalẹnu mi-in lo n jade lẹnu ọpọ awọn to wa nitosi otẹẹli naa nigba ti wọ gbọ iroyin iku Oluyẹmi.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ko si nnkan to ṣe Oluyẹmi ko to di pe o lọ sun lalẹ ọjọ Ẹti, ṣugbọn nigba to di aarọ kutu ọjọ keji, ni wọn sọ pe ko jade sita lasiko to yẹ ko jade.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa, Taiyelolu ni wọn sọ pe o lọ si yara ti Oluyẹmi n sun si lati pe e. Gbogbo bi wọn ṣe sọ pe Taiye n pe e ni ko dahun, to si tun ti tilẹkun yara naa lẹyin.

Igba to ya ni wọn sọ pe Taiyelolu fipa ja ilẹkun naa wọle, to si jẹ pe oku Oluyẹmi lo ba lori ibusun rẹ, eyi lo jẹ ko pariwo sita fawọn eeyan.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla sọ pe kayeefi niṣẹlẹ ọhun jẹ nigba ti wọn fi to ẹkun ileeṣẹ wọn to wa ni Oke-Itoku jẹ.

Odutọla sọ pe awọn ọlọpaa Oke-Itoku ni wọn sare lọ sibẹ lati mọ ohun to ṣẹlẹ, to si ni wọn ko ri apa kankan lara oloogbe naa, leyi ti wọn ko ba sọ pe boya oun atẹnikan jọ wọya ija loru mọju.

Siwaju sii lo ni bo tilẹ jẹ pe awọn ti gbe oku Oluyẹmi lọ si mọṣuari ile iwosan ijọba to wa ni Ijaye, sibẹ iyẹn ko sọ pe k’awọn ma ṣe gunle iwadii lati mọ ẹkunrẹrẹ nipa iku to pa oloogbe naa.

Odutọla fi kun ọrọ rẹ pe ẹka ileeṣẹ wọn to n ri si iwa ọdaran, SCID ti gba iṣẹ iwadii naa ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI