Ariwo ibanujẹ nla lo sọ niluu Ipokia laipẹ yii nigba ti iji lile wo ogiri ile-ẹkọ, to si pa akẹkọọ kan to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla danu.
Ile-ẹkọ girama Mayigi, iyẹn Mayigi Community Comprehensive High School to wa niluu Ilaṣẹ, ijọba ibilẹ Ipokia, ipinlẹ Ogun ni wọn sọ pe iji lile wo ogiri kilaasi rẹ danu.
Timothy Amosun to jẹ akẹkọọ to wa nipele kẹta, JSS3 ni wọn sọ pe o ba iku ojiji pade nibi iṣẹlẹ abami naa.
Yatọ si Timothy to doloogbe nibi ijamba ọhun, akẹkọọ marun-un miran, olukọ meji, iya olounjẹ ati ọmọ rẹ, ọmọ oṣu mẹjọ naa tun fara kaaṣa, ti wọn si farapa.
Niṣe lọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna nigba ti wọn sọ pe iji lile naa bẹrẹ, ti onikaluku si bẹrẹ sii sa asala fun ẹmi ara wọn.
Awọn ara agbegbe naa la gbọ pe wọn sare lọ sibẹ lati ṣe iranwọ lasiko ti ogiri ọhu ya lulẹ, koda ti paanu orule rẹ naa tun ya.
Lara awọn to gbe iroyin naa si wa leti jẹ ko di mimọ pe gbogbo ogiri ile ẹkọ naa lo ti dẹnukọlẹ tẹlẹ, ti wọn si n woju ijọba fun atunṣe lati bi ọdun meloo kan sẹyin.
Yatọ si ogiri ile-ẹkọ naa, wọn ni gbogbo paanu ati ipo ti ile ẹkọ naa wa bo bojumu to fun eto ẹkọ, ati pe niṣe lawọn olukọ ati akẹkọọ n rọju lati kẹkọọ.
Gomina Dapọ Abiọdun nigba to n sọrọ, ba awọn to kagbako ninu ijamba naa kẹdun, paapaa mọlẹbi Timothy to padanu ẹmi rẹ.
Abiọdun sọ pe ijọba yoo gbe gbogbo bukata itọju awọn to farapa titi ara wọn yoo fi ya, ati pe oun ti paṣẹ fun awọn ileeṣẹ tọrọ naa kan lati gbe oun to farapa lọ sibi ti wọn yoo ti gba itọju to pe ye.
Bakan naa lo sọ pe oun ti paṣẹ fun Kọmiṣanna feto ẹkọ lati lọ sile mọlẹbi ọmọ to ku, lati ba wọn kẹdun, ati awọn to farapa.
Bẹẹ lo sọ pe ki kọmiṣanna naa ṣabẹwo sile-ẹkọ ọhun lati le mọ bi wọn yoo ṣe tun un kọ.
No comments:
Post a Comment