Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ ifẹnukonu tawọn Wolii ijọ Kerubu ati Serafu kan ṣe nita gbangba nibi eto tita ami ororo le ara wọn lori ṣi n jẹ kayeefi f'ọpọ awọn eeyan.
Fọnran kan lo lu sita lori ikanni ayelujara lọjọ Aiku tii ṣe Sannde to kọja yii, nibi ti olori ijọ Kerubu kan ti n ta ami oro ati omi le ọkan lara awọn ojiṣe Ọlọrun ninu ijọ naa lori.
Nibi eto naa ni agba Wolii ọhun ti n ṣe adura pẹlu orukọ Mose Orimọlade ati awọn agba ijọ Kerubu bii Timothy Adedayọ Ogunnusi ati awọn miran gbadura fun Biṣọọbu tuntun naa.
Bakan naa ni agba Wolii naa tun fi orukọ Baba, ọmọ ati Ẹmi Mimọ gbadura fun alagba tuntun ọhun.
Lẹyin eyi lo bu omi naa sẹnu Biṣọọbu naa lori ikunlẹ to wa. Bi wọn ṣe pari ni agba Wolii naa yọ ahọn rẹ sita, to fi kan ahọn Biṣọọbu to wa lori ikunlẹ lẹẹmẹta ọtọọtọ, leyi ti wọn ni aṣẹ ni wọn fi ṣe e.
Oriṣiriṣi ọrọ lo ti jẹyọ lori ayelujara latigba ti fọnran naa ti jade, tọpọ awọn eeyan si n bu ẹnu ẹtẹ lu igbesẹ naa.
Bawọn kan ṣe n sọ pe igbesẹ naa ko yatọ si ibalopọ takọ-takọ ti wọn n gbe larugẹ, bẹẹ lawọn miran n sọ pe iwa naa ko bojumu to, ati pe alailojuti lawọn ti wọn n fi orukọ Jesu boju naa.
Zainab Ọmọwunmi sọ pe
“Subhanaalahi.....njẹ a tiẹ le fopin si ọrọ adari ẹlẹsin, abi iru palapala wo ree.”
Ayọmide Babatunde ninu ọrọ rẹ sọ pe
“Ẹyin Pasitọ ati ẹyin Aafa lẹ maa ba aye yi jẹ. Ẹyin oloribuu wọnyi. Eeeyan buruku nibigbogbo.”
Azeezat Ọlajuwọn sọ pe
“Mo ti sọ pe awọn pasitọ ati aafa ni wọn maa ba orileede yii jẹ.”
Hajia Sufficient Ajọke Ṣomuyiwa ninu ọrọ rẹ sọ pe
“Eru fun Eru, Erupẹ fun Erupẹ, Kissing fun kissing. Ko yẹ ki baba ṣe iru nnkan bayii nita gbangba. Eleyii buru jai.”
Ọdunayọ Ọlaniyan-Akindele ninu ọrọ rẹ sọ pe
“Oriṣiriṣi, ibi ti ẹ ba aye jẹ de, awọn ọmọ yin a jẹ ninu ẹ.”
Ṣugbọn ṣa, ọkunrin kan to pe orukọ rẹ ni Oriade Ipọṣọla Ajetẹlu ti sọ pe ki gbogbo ẹni ti ko ba mọ ohun to ṣẹlẹ ninu fọnran naa gbe ẹnu wọn dakẹ, ki wọn ma ba a ṣẹ si Ọlọrun.
“Ẹ dakun, bi ko ba ye e yin, ẹ dakẹ ẹnu yin. Kii ṣe gbogbo ohun ti ẹ ba ri lo tunmọ si ero ọkan yin. Ifẹnukonu ori ahọn jẹ ọna to lagbara nipa ṣiṣe paṣipaarọ okun. Baba naa ko le ṣe iru nnkan bẹẹ nita gbangba ti erongba wọn ba jẹ buburu,” Ajetẹlu sọ bẹẹ
Bakan naa, Debby Ọdun Ọdunsi naa sọ pe
“Fun ẹyin ti ẹ gbe fọnran yii sori ayelujara...were ni ẹni naa... Baba yii n gbe agbara rẹ fun ọkunrin naa lọna to mọ ni... Ko yẹ ki iru fọnran yii jade sori ayelujara... Palapala ni eyi jẹ, ni titemi o... Bi baba ba fẹẹ pa, ko lọ ba iyawo rẹ.”
No comments:
Post a Comment