Miliọnu kan naira ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United kọọkan gba lẹyin ti wọn bori ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Nasarawa United - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 27, 2025

Miliọnu kan naira ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United kọọkan gba lẹyin ti wọn bori ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Nasarawa United


Idunnu lo pada ṣubu lu ayọ awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United nigba ti baba olowo kan fi ẹbun owo nla-nla ta wọn lọrẹ.
 
Ko ṣai ri bẹẹ, bi ko ṣe pe aṣeyọri wọn lo mu ẹbun nla naa jade.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii ni ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United koju akẹgbẹ wọn, iyẹn Nasarawa United ni gbagede Rashidi Yekini Main Bowl to wa ni papa iṣere George Innih niluu Ilọrin.
 
Nibi ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni Kwara United to fẹyin Nasarawa United gbolẹ pẹlu aami ayo kan si odo.

Ọkan pataki lara awọn ololufẹ Kwara United, Bashorun Kayode Bankole lo fi ẹbun owo naa ta awọn agbọọlu ọhun lọrẹ.

Miliọnu kan naira ni agbabọọlu kọọkan gba lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ọhun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Kwara United ti wa sun soke si ipo kẹwaa lori tabili idije naa.

Wọn yoo si tun koju akẹgbẹ wọn lati ipinlẹ Plateau, iyẹn Plateau United lopin ọsẹ yii ni ọsẹ kejilelọgbọn idije naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI