Iṣẹ akanṣe idagbasoke lo ti bẹrẹ lopopona Ibrahim Taiwo to wa niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara.
Eyii ni afojusun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati mu ayipada ọtun ba awọn opopona to wulo faraalu.
Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Ọgbẹni Olayinka Fafoluyi tọpọ mọ si Solace fi sita laipẹ yii, o ni opopona naa wa lara awọn opopona to jẹ gomina logun lati mu idagbasoke ba.
O ni eyi ni lati mu itẹsiwaju ba gbogbo opopona fun idagbasoke awọn opopona lagbagbe ati igberiko ilu naa.
Solace ni opopona Ibrahim Taiwo jẹ ọkan pataki lara awọn opopona to wulo fun igbokegbodo ọkọ nipa eto ọrọ aje, to si n mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ilu Ilorin.
O ni laipẹ, wọn yoo pari atunṣe naa.
No comments:
Post a Comment