Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ Pentecostal Sanctuary Bible Ministries, Wolii Sunday Dare Iyunade ti rọ ijọba Naijiria lati dẹkun titẹti si tabi gbigba amọran lati ọdọ ajọ eleto iṣuna lagbaye bii Banki agbaye, IMF, Chattered House ati awọn miran, bi wọn ba fẹẹ ni itẹsiwaju ati idagbasoke ninu eto ọrọ aje wọn.
Wolii Iyunade lo sọrọ naa lonii ọjọ Iṣẹgun, Tusidee nibi ipade awọn akọroyin to pe lati fi saani ayẹyẹ idasilẹ ijọ naa, ati ipagọ wọn to bẹrẹ lọsẹ yii.
Ọdun kọkandinlọgbọn ree ti wọn da ijọ naa silẹ ni ojule kẹsan , adugbo Araromi, lagbegbe Odo-Ẹgbọ niluu Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun.
Agba Wolii naa, nigba to n sọrọ nipa eto ọrọ aje ati ọjọ iwaju Naijiria, jẹ ko di mimọ pe ohun ti ko dara ni fun ilẹ Naijiria lati maa gba amọran nita.
"Awọn adari Naijiria ni lati dẹkun titẹti si tabi gbigba amọran lati ọdọ ajọ eleto iṣuna agbaye yoowu bii Banki Agbaye, IMF, Chattered House ati awọn miran," Wolii Iyunade sọ bẹẹ.
O ṣalaye pe kii ṣe awọn amọran naa ni yoo da Naijiria pada bọ sipo, ti ko si nii ṣe anfaani kankan fun eto ọrọ aje wọn, ati pe ki wọn tẹle awọn ilana ati agbekale ti wọn ti ṣeto fun igbelarugẹ eto ọrọ aje fun Naijiria.
"Kii ṣe amọran wọn lo maa mu Naijiria pada bọ sipo, eyi ti yoo mu ki eto ọrọ aje Naijiria dagba, ki wọn tẹle awọn ilana ati agbekale ti wọn ti gbe kalẹ fun ilẹ naa.
"Bi wọn ba tẹle awọn ilana ti wọn ti ṣagbekalẹ rẹ, eto ọrọ aje yoo pada bọ sipo, ohun gbogbo yoo si ṣe daadaa."
Siwaju sii ni Wolii Iyunade jẹ ko di mimọ pe adari kan ṣi n bọ, ti yoo pari gbogbo ilana ati agbekalẹ ti iṣakoso to wa ni Naijiria lasiko yii n ṣe, ati pe eto ọrọ aje ilẹ naa yoo ṣe daadaa.
Nigba to n ṣalaye bi eto ayẹyẹ idasilẹ ọdun kọkandinlọgbọn ati ipagọ ọdun kẹtalelogun naa yoo ṣe lọ, Wolii Iyunade ṣalaye pe lọjọ Aiku, ọjọ kẹrindilogun, oṣu yii, wọn yoo ṣe ipolongo kaakiri igboro ni deedee agogo mẹta ọsan.
Isọji ita gbangba yoo waye lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun si Ọjọbọ, ogunjọ, oṣu yii ninu ijọ naa, eyi yoo waye ni deedee agogo marun-un irọlẹ, ojoojumọ.
Ipade awọn iranṣẹ Ọlọrun ati oṣiṣẹ yoo waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun si Ọjọbọ, ogunjọ oṣu yii nile ijọsin naa, laaarin agogo mẹsan aarọ si agogo meji ọsan.
Wolii Sunday Dare Iyunade ninu atẹjade to fawọn akọroyin sọ pe oniruuru awọn iranṣẹ Ọlọrun ni wọn ti ranṣẹ pe lati wa ṣe idanilẹkọọ lori awọn akọle loriṣiriṣi to jẹ mọ akori ayẹyẹ tọdun yii, eyi ti wọn pe ni "EL-SHADDAI - More than Enough", ti wọn yọ lati inu Bibeli, Jẹnẹsisi ori karundinlogoji, ẹsẹ kọkanla (Gen 35:11).
O tẹsiwaju pe aṣalẹ orin iyin yoo waye lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii nile ipagọ wọn to wa ni Zion City, loju ọna Atan-Eruwon, bẹrẹ lati agogo mẹwaa alẹ, ti ilẹ yoo fi mọ.
Lati kadi eto naa nilẹ, eto ayẹyẹ isin idupẹ yoo waye lọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii nilẹ ipagọ naa, ni deedee agogo mẹsan owurọ.
Gbogbo eto naa ni wọn yoo ṣafihan wọn lori ikanni ayelujara ṣọọṣi naa ni Facebook ati Youtube.
No comments:
Post a Comment