Ijọba Kwara gbẹsẹ le awọn iwe aṣẹ alẹmọde tọdun 2024 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 17, 2025

Ijọba Kwara gbẹsẹ le awọn iwe aṣẹ alẹmọde tọdun 2024


Ijọba Kwara ti sọ pe awọn iwe aṣẹ patako alẹmọde ti ọdun 2024 ti ba ọdun naa lọ, ko wọ ọdun tuntun yii.
 
Alaga ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn patako alẹmọde kaakiri ipinlẹ naa, Kwara State Taskforce Committee on Illegal Billboards and Signages ati Kọmiṣanna feto iroyin, Ọnarebu Bolanle Olukoju ninu atẹjade ti wọn fi sita sọ pe awọn ko le gba ayederu awọn patako alẹmode mọ.
 
Wọn ni ọsẹ yii ni igbesẹ yoo bẹrẹ lati bẹrẹ sii yọ gbogbo awọn patako alẹmode ti wọn ko san owo tuntun le lori lai nii wo ileeṣẹ to jẹ.

Atẹjade naa sọ pe igbesẹ yii lo lọ nibamu pẹlu agbekalẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori eto idagbasoke ilu, ati lati mu ipinlẹ Kwara lọ sipo ti yoo fa awọn ileeṣẹ mọra.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI