Lẹyin gbedeke ọjọ meje tijọba ipinlẹ Kwara fun gbogbo awọn ileeṣẹ to n lo patako ipolowo kaakiri ipinlẹ naa, igbimọ agbofinro tijọba ṣagbekalẹ rẹ ti bẹrẹ sii yọ awọn paatako ọhun danu.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ijọba sọ pe gbogbo owo patako ipolowo tawọn ileeṣẹ naa san ti ba ọdun 2024 to kọja lọ, ati pe wọn yoo bẹrẹ sii san awọn owo tuntun miran fun ọdun 2025.
Ijọba sọ pe gbogbo awọn ti ko ba tii san owo patako ipolowo wọn fun ọdun 2025 ni ki wọn tete lọ san an ko too to ọjọ meje, bi bẹẹ kọ, wọn yoo bẹrẹ sii fa wọn tu.
Ọjọ meje ọhun la gbọ pe o ti pe bayii, eyi to mu kawọn agbofinro ti ileeṣẹ to n ri sọrọ patako ipolowo naa ti a mọ si Signage bẹrẹ iṣẹ lati maa yọ awọn patako ọhun danu.
Bi wọn ṣe n yọ awọn patako yii niluu Ilọrin, bẹẹ naa ni wọn n yọ ọ lawọn ilu to ku nipinlẹ ọhun, ni ibamu pẹlu ofin ati agbekalẹ ijọba.
Lara awọn to fi iroyin naa to wa leti sọ pe awọn agbegbe bii Unity Road, Post Office, Maraba, Fate Roundabout, Tanke Junction, Flower Garden, Oja Oba, Surulere, Airport Road ati garaaji Offa ni wọn ti bẹrẹ sii yọ awọn patako ipolowo naa danu, paapaa awọn to kọ lati san owo tuntun.
No comments:
Post a Comment