Ọna ara-ọtọ ni eto iṣunu aawẹ Ramadaani ati Lẹnti gba yọ nipinlẹ Kwara pẹlu bi Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe pe apejẹ iṣinu fawọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi.
Amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Kọmureedi Olayinka Fafoluyi tọpọ mọ si Solace lo ṣagbatẹru eto naa ni gbagede Flower Garden to niluu Ilorin lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun ti a wa yii.
Ọpọ awọn ọdọ ati alẹnulọrọ kaakiri ipinlẹ naa ni Fafoluyi gba lalejo lati jọ ṣinu aawẹ Ramadaani ati Lẹnti to n lọ lọwọ.
Eyi lo waye lẹyin ọjọ marun-un ti Gomina AbdulRazaq ti pe apejẹ iṣinu fawọn akọroyin ijọba ati awọn oludasilẹ iroyin ayelujara ati awọn gbajumọ lori ayelujara nipinlẹ naa.
Nigba to n sọrọ, Fafoluyi sọ pe lati ṣagbelarugẹ ifẹ ati iṣọkan laarin awọn ọdọ ati ẹlẹsin mejeeji.
Lara awọn to tun wa nibi apejẹ ọhun ni Kọmiṣanna feto ile gbigbe ati idagbasoke ilu, Ọnarebu Ibrahim Akaje, oludamọran Saddiq Buhari, amugbalẹgbẹ Ọnarebu AbdulSalam Wasiu, amugbalẹgbẹ lẹgbẹ tẹlẹ, Ọnarebu Mubarak Bello ati oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu Labour nigba kan, Basambo Abubakar.
Eto ọhun ti Ọnarebu Ibrahim Akaje jẹ alaga rẹ, lo tun so gbogbo awọn Kọmureedi ni oriṣiriṣi ẹka, to fi mọ eto ẹkọ kaakiri ipinlẹ naa.
Aworan
No comments:
Post a Comment