Gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lo gbọdọ kopa ninu eto iforukọsilẹ KWSRA - Gomina AbdulRazaq pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, March 9, 2025

Gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lo gbọdọ kopa ninu eto iforukọsilẹ KWSRA - Gomina AbdulRazaq pariwo sita


Lojuna lati ni akọsile iye awọn olugbe ipinlẹ Kwara, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ki gbogbo araalu lọ ṣe iforukọsilẹ pẹlu ijọba.

Gomina Abdulrazaq lo ṣe ikede naa lopin ọsẹ to kọja yii, to si ni anfaani nla ni yoo jẹ fun gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa, paapaa lati ni nọmba aabo ti wọn pe ni SSID, iyẹn State Security Identification, ti wọn yoo si tun gba kaadi

Gẹgẹ bi adele alakoso agba fun ajọ to n ri sọrọ eto iforukọsilẹ (KWSRA) naa, Tajudeen Jimọh, ṣe ṣalaye, o sọ pe ojuṣe ijọba ni lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu fun ilana idagbasoke eto ọrọ aje, eyi to rọ mọ iforukọsilẹ awọn araalu.

Jimoh sọ pe, “A ti bẹrẹ eto naa kaakiri ibudo iforukọsilẹ mẹrindinlọgọrun to wa nipinlẹ yii. A tun ṣi ni erongba lati ṣagbekalẹ ibudo iforukọsilẹ sii bi a ṣe n tẹsiwaju.

“Bakan naa la tun n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ileeṣẹ bii eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan, ileeṣẹ eto ẹkọ giga, ijọba ibilẹ ati oye jíjẹ, to fi mọ Kwara State Social Investment Programmes, ati awọn miran lojuna lati jẹ ki ipolongo naa to gbogbo araalu leti.

“A ni lati fi da a yin loju pe awọn obi, alagbatọ ati awọn akẹkọọ yoo nilo nọmba SSID yii bi wọn ba fẹẹ forukọsilẹ fun idanwo, eto ẹkọ ọfẹ, owo iranwọ, ati awọn anfaani miran lawujọ.”

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn akẹkọọ ti wọn ba fẹẹ wọle s'awọn ile ẹkọ giga to jẹ tijọba yoo nilo lati forukọsilẹ gẹgẹ bi olugbe ilu, ati pe ẹnikẹni ti yoo ba fẹẹ jẹ anfaani ijọba gbọdọ forukọsilẹ fun nọmba idanimọ SSID naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI