Gbogbo igba la ma maa ṣatilẹyin fawọn oniṣẹ-ọwọ - Ijọba Kwara fọkan araalu balẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 22, 2025

Gbogbo igba la ma maa ṣatilẹyin fawọn oniṣẹ-ọwọ - Ijọba Kwara fọkan araalu balẹ


Ijọba ipinlẹ Kwara ti fọkan awọn araalu balẹ nipa ṣiṣe atilẹyin fawọn oniṣẹ ọwọ ati oniṣowo nipinlẹ naa.
 
Alakoso agba fun ileeṣẹ Kwara State Public Procurement Agency (KWPPA), Raheem Abdulbaki lo fidi ọrọ naa mulẹ lasiko abẹwo to ṣe lọ si ileeṣẹ HHL Insurance Brokers Limited laipẹ yii.
 
Nibẹ lo ti sọ pe lara awọn afojusun ileeṣẹ naa ni agbelarugẹ si okoowo ati iṣẹ-ọwọ alabọde tawọn araalu  n ṣe.
 
O ni ọdun kẹrin ree tawọn ti wa lori iṣẹ naa, tawọn si ti ko ipa ribiribiri lori okoowo ati iṣẹ-ọwọ araalu. 

O jẹ ko di mimọ pe ilana ti awọn gbe sita ni pe gbogbo oniṣẹ owo ati olokoowo ni wọn jẹ anfaani akanṣe iṣẹ tijọba n gbe jade, lati le jẹ ki idagbasoke ba okoowo ati iṣẹ ti wọn yan laayo, to si n ṣagbelarugẹ fun idaṣẹsilẹ.
 
Nibẹ lo ti gboriyin fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori akitiyan rẹ nipa iranlọwọ fawọn araalu, eyi to lo jẹ ki awọn maa ni akọsilẹ aṣeyọri nla.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI