Tọkantọkan lawọn ọmọ bibi ati olugbe ipinlẹ Kwara fi n ṣe adura fun amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori eto iroyin igbalode nipinlẹ naa, Kọmureedi Michael Ọlayinka Fafoluyi lori bo ṣe pin ẹbun aawẹ Ramadaani ati ti lẹnti to n lọ lọwọ fawọn araalu.
Ọjọ Ẹti to kọja yii ni iṣẹlẹ ọhun waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Lọjọ naa, Fafoluyi tọpọ awọn eeyan tun mọ si Solace lo pade awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara bii aalga ijọba ibilẹ Irẹpọdun, Ọnarebu Abdulazeez Tinuola Yakub ati Ọnarebu Olushola Odetundun toun n ṣoju agbegbe Irepodun nile igbimọ aṣofin.
Awọn mẹtẹẹta yii ni wọn lọ ṣeapde pẹlu awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC ninwọọdu Ipetu, Rore ati Aran-Orin, nibi ti wọn ti sọ oriṣiriṣi ọrọ to nii ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu naa.
Nibi ipade naa ni wọn ti gbe oṣuba kare fawọn ọmọ ẹgbẹ, ti wọn si rawọ ẹbẹ s'awọn ti inu n bi lori ọrọ oṣelu to waye kọja.
Wọn tun rọ awọn eeyan lati lo anfaani asiko aawẹ Ramadaani ati Lẹnti to wa nita lati fi yanju gbogbo aawọ to ba wa nilẹ.
Nibi ipade naa lo ti lo anfaani rẹ lati pin ẹbun aawẹ fawọn eeyan, to si tun ṣeleri pe oun yoo tun tẹsiwaju laipẹ, paapaa fawọn ọmọ ẹgbẹ.
Awọn eeyan naa dupẹ gidigidi lori akitiyan Fafoluyi, paapaa bo ṣe n tọpasẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nipa adari ati ninawọ ifẹ.
Lẹyin naa, alaga ijọba Irepodun, Ọnarebu Abdulazeez Tinuola Yakub mu Solace kaakiri awọn akanṣe iṣẹ to ti ṣe fun idagbasoke ipinlẹ naa.
Aworan:
No comments:
Post a Comment