Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba gbajugbaja elere idaraya ọmọ ipinlẹ naa, Eniola Bolaji yọ lori bo ṣe gbarada nibi idije Badminton to waye lorileede Spain laipẹ yii.
Eniola lo gbegba oroke, to si gba aami ẹyẹ goolu nibi idije agbaye ti keji to waye ni Spain.
Ṣaaju asiko yii ni ọmọ bibi ipinlẹ Kwara naa ti jawe olubori gẹgẹ bi ẹni to dara julọ ninu idije naa nilẹ Afrika.
Nigba to n gbe oriyin fun Bolaji, Gomina AbdulRazaq sọ pe ọkan akikanju ati ipinnu rere ti ọmọbinrin naa ṣe, lo jẹ ko maa tayọ laaarin awọn akẹgbẹ rẹ.
Gomina Abdulrazaq sọ pe lara awọn nnkan to tun n jẹ ki Bolaji maa leke ni ti iwa ikora-ẹni-nijanu, ati bo ṣe n farajin fun ere idaraya naa.
Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun un, lori bo ṣe n jẹ aṣoju ipinlẹ naa si rere kaakiri agbaye, pẹlu amọran lati ma ṣe rẹwẹsi.
No comments:
Post a Comment