Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti rọ gbogbo ọmọ lẹyin Anọbi lati lo anfaani asiko aawẹ Ramadaani to wa nita yii lati fi gbadura fun aabo lorileede Naijiria.
Gomina AbdulRazaq sọ pe yatọ si aabo, ki wọn tun gbadura fun aṣeyọri, ati agbara fun ilẹ Naijiria, paapaa ipinlẹ Kwara.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi lọjọ Ẹti to kọja, gomina gbadura pe ki oṣu aawẹ naa mu ibukun rẹpẹtẹ wa fun araalu.
Nigba to ba awọn musulumi ṣajọyọ pẹlu awọn musulumi, ati kiki wọn kaabọ sinu oṣu alapọnle naa, gomina sọ pe ki wọn bọwọ fun oṣu naa, ki wọn si maa wa ni iwa mimọ.
Bakan naa lo tun ki Emir ilu Ilorin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari kaabọ sinu oṣu aanu, eyi ti iwe mimọ Kiraani fi han Muhammad.
No comments:
Post a Comment