‘Ki lo ṣẹlẹ, asasi abeedi’, lọrọ kayeefi o n jade lẹnu awọn ara agbegbe Kaltungo to wa nijọba ibilẹ Kaltungo, ipinlẹ Gombe nigba tiwọn ri ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Maryam Samuel bo ṣe gbẹmi ara rẹ lojiji.
Ọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii ni Maryam lọ pokunso si ori igi kan to wa ninu igbo, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Buhari Abdullahi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ fawọn akọroyin pe ko ju bi wakati mẹrinlelogun ti Maryam jade nile wi pe oun fẹẹ lọ wa igi idana ninu oko, ti wọn ba oku rẹ lori igi to so ara rẹ kọ si.
Abdullahi sọ pe “Ni nnkan bi agogo mẹsan aarọ, wọn fi iṣẹlẹ iku nipa pipokunso to ẹkun ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Kaltungo leti, Baalẹ abule Kalarin lo lọ sọ.
“A wa pada mọ orukọ oloogbe naa pe Maryam Samuel, ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo n jẹ, ti a ba oku rẹ pelu okun lori igi ni ori oke Kalarin, lai ni apa kankan lara,” o sọ bẹẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o lawọn ti gbe oku naa lọ si mọṣuari ile iwosan ijọba to wa ni Kaltungo.
No comments:
Post a Comment