Awọn darandaran ge Akin, gbajumọ agbẹ l'Ọyọ lọwọ lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 22, 2025

Awọn darandaran ge Akin, gbajumọ agbẹ l'Ọyọ lọwọ lọ


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti fidi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti tẹ darandaran kan ti wọn furasi pe o wa lara awọn to ge agbẹ kan ni ika ọwọ meji.
 
John Akin la gbọ pe o da oko si abule Ilowa Gbade to wa nijọba ibilẹ Atiba, ipinlẹ Ọyọ, nibi ti awọn darandaran ti lọ fi maalu jẹ oko rẹ.
 
Wọn ni Akin wa ninu oko rẹ, to si n ṣiṣẹ lọwọ lasiko tawọn darandaran yii da maalu wọnu oko rẹ.
 
Lara awọn to fiṣẹlẹ ọhun to wa leti sọ pe loju ẹsẹ ni Akin ti bẹrẹ sii bẹ awọn darandaran naa lati ko maalu wọn kuro ninu oko oun, ati pe oun ko fẹ ki wọon da oun ni gbese.
 
Niṣe ni wọn sọ pe awọn darandaran naa bẹrẹ sii lu Akin, ti wọn si luu lalubami, ko too di pe wọn ge ika ọwọ rẹ meji lọ.
 

Ariwo ti wọn ni Akin pa, lo mu kawọn to wa nitosi sare debẹ, to si jẹ iyalẹnu fun wọn, eyi lo jẹ ki wọn le wọn mu, to si jẹ pe ẹnikan ni wọn ri mu.
 
Nibẹ ni wọn ti lọ fa a le awọn ọlọpaa ẹkun Atiba to wa nitosi lọwọ, ti wọn si fiṣẹlẹ naa to wọn leti.
 

A gbọ pe kii ṣe igba akọkọ ree tawọn darandaran yoo maa lọ fi maalu jẹko ninu oko awọn ara abule naa ree, ti ọrọ naa si ti n kọ ọpọ lominu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI