Àwọn aráàlú bẹ̀rẹ jíjẹ ànfààní omi ẹ̀rọ ìgbàlódé ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 17, 2025

Àwọn aráàlú bẹ̀rẹ jíjẹ ànfààní omi ẹ̀rọ ìgbàlódé ní Kwara


Ko sẹni to de ipinlẹ Kwara, paapaa ilu Ilorin lasiko yii, ti ko nii mọ pe ayipada rere ti de ba eto omi ẹrọ igbalode, to si fọkan awọn araalu balẹ pe opin ti de ba gbogbo idakureku lilo omi gidi.

Opin ọsẹ to kọja yii ni Kọmiṣanna feto omi nipinlẹ naa, Usman Yunusa Lade ṣabẹwo s'awọn agbegbe ti omi ẹrọ ijọba ti n yọ, ati bawọn araalu ṣe n ṣe amulo rẹ si.

Lara awọn agbegbe to ṣabẹwo si ni Adeta, Sakele, Pakata, Ita-merin, Oloje, Alore, Abayawo, Okelele, Ayegbami, atawọn miran.
 
Nibẹ ni Kọmiṣanna ti jẹ ko di mimọ pe fun anfaani lilo araalu ni awọn omi ẹrọ igbalode tijọba n ṣe naa, ati pe lati le mu igbe aye irọrun fawọn araalu ni.
 
Bakan naa ni Ọnarebu Usman Yunusa Lade tun ṣabẹwo si awọon ibudo omi ẹrọ igbalode bii Flower Garden waterway ati Pakata waterway, nibi ti iṣẹ akanṣe ati atunṣe ti n lọ lọwọ.

O rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati ṣamulo awọn omi ẹrọ igbalode naa daadaa, ki wọn si daabo bo gbogbo rẹ daadaa lọwọ to n ba dukia ijọba jẹ. 
 
O fi kun ọrọ rẹ pe ki awọn araalu ma ṣe bo ẹnu wọn, bi wọn ba ri awọn ọpa omi to n jo lagbegbe wọn fun atunṣe loju ẹsẹ, nitori pe igbayegbadun araalu lo jẹ ijọba logun.

O ni bi atunṣe ibudo omi ti Flower Garden ba pari patapata, yoo wulo pupọ fawọn ara agbegbe bii Sabo-Oke, Amilengbe, Maraba, Adualere, Mubo, ati Ipata.
 
Bakan naa lo fi kun un pe atunṣe ibudo omi ti Pakata yoo wulọ pupọ fun awọn ara agbegbe bii Abeemi, Omoda, Ile Ara-Oyo, Masingba, Ajikobi, Okekere, Popo-Igbona, Ita-Ogunbo, Ita-Kudimo, Ode Alfa Nda ati Agbaji, ati awọn miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI