Awọn alakoso ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United ti sọ pe ko si otitọ ninu iroyin to n lọ kaakiri ori ayelujara wi pe Sẹnetọ kan nipinlẹ Kwara san owo silẹ fun awọn eeyan lati woran ifẹsẹwọnsẹ laarin ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United ati akẹgbẹ wọn, Nasarawa United.
Wọn jẹ ko di mimọ pe ijọba ipinlẹ naa lo buwọ luu pe ki awọn ololufẹ ere idaraya, paapaa awọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji lati lọ wo ifẹsẹwọnsẹ naa lọfẹẹ.
Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ agbọọlu naa, Ọgbẹni Kumbi Titiloye, fi sita nipasẹ alakoso agba, Malaamu Bashir Badawiy, o sọ pe ko si ẹnikankan tabi ẹgbẹ kankan, tabi sẹnetọ kankan to ṣagbatẹru wi wo iran ifẹsẹwọnsẹ naa lọfẹẹ.
Ifẹsẹwọnsẹ naa ti wọn lo waye ni deedee agogo mẹrin irọlẹ Ọjọru, ọsẹ yii ni gbagede Rashidi Yekini Main Bowl, ti papa iṣere George Inih Stadium, niluu Ilorin.
Badawiy ninu atẹjade naa rọ awọn ololufẹ ere idaraya nipinlẹ naa lati lo anfaani ọhun lati lọ woran, ki wọn si le fun awọn ikọ Harmony ni koriya lati le yege ninu idije naa.
O wa gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ati alaga ajọ to n ṣabojuto ere idaraya, Mallam Bola Magaji, lori akitiyan wọn lati maa ṣagbatẹru idagbasoke ere idaraya nipinlẹ naa.
Ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United lo pada bori pẹlu aami ayo kan si oodo, nigba ti Abayomi Lawal gba bọọlu sinu awọn ni deedee iṣẹju mẹrinlelọgọta, iyẹn saa keji.
No comments:
Post a Comment