Ko din ni akẹkọ ile ẹkọ girama mẹjọ ti wọn ti wa lahamọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lori ẹsun ṣiṣe ẹgbẹ okunkun ati idunkooko mọ awọn akẹgbẹ wọn.
Ilu Ifọ, ijọba ibilẹ Ifọ lọwọ palaba awọn mẹjọ naa ti segi lasiko ti wọn n lọ awọn akẹkọọ ẹgbẹ wọn lọwọ gba.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, igbakeji ọga agba ile-ẹkọ girama ti Ifọ, iyẹn Ifo High school, Ọgbẹni Alako Oluwọle ni wọn lo lọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, wi pe awọn akẹkọọ kan ti da ẹgbẹ okunkun silẹ ninu ile-ẹkọ wọn, ati pe wọn tun fi n lọ awọn akẹgbẹ wọn lọwọ gba ninu ọgba.
O sọ pe o ti pẹ ti awọn ti n fura wi pe awọn akẹkọọ wọn n ṣẹgbẹ okunkun, ti wọn si tun n ṣe e ninu ọgba ile-ẹkọ, paapaa lasiko ti eto ẹkọ ba n lọ lọwọ.
Igbakeji ọga ile-ẹkọ naa sọ pe ọpọ akẹkọọ ni wọn ti dunkooko mọ lati lọ wọn lọwọ gba, eyi to ko ibẹrubojo sọkan ọpọ awọn akẹkọọ.
Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla nigba to n fidi iroyin ọhun mulẹ fawọn akọroyin niluu Abẹokuta lopin ọsẹ to kọja, o ni nnkan bi agogo mejila kọja iṣẹju marun-un, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2025 ni wọn wa fọrọ ọhun to ọlọpaa leti.
Odutọla ni Oluwọle ati ọkan lara awọn olukọ ile-ẹkọ naa, Akinṣẹku Ọlọruntọba Julius ni wọn jọ lọ teṣan lati fidi rẹ mulẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni Ọmọlaṣọ Waris, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; Bennett Bolawatifẹ, ọmọ ọdun mẹẹdogun; Aluko Taiwo, ọmọ ọdun mẹẹdogun; Akinọla Ifẹoluwa, ọmọ ọdiun mẹrindinlogun; Azeez Hassan, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; Kilani Babatunde ti wọn n pe ni Ṣọja, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; Kẹhinde Aluko, ọmọ ọdun mẹẹdogun ati Faṣẹdemi Samuel toun naa jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni awọn tọwọ tẹ.
O ni ẹgbẹ okunkun ti wọn pe ni Future Guys (F.T.G.) ni awọn ọmọ naa n ṣe, ati pe awọn akẹkọọ agba meji kan, Ebenezer Ọpẹ to jẹ Aarẹ wọn ati Ebenezer Tobi, ti wọn jọ wa ni SSS 1 lo ko gbogbo wọn wọle sẹgbẹ naa.
Odutọla ti wa jẹ ko di mimọ pe ọga awọn, Lanre Ogunlọwọ ti paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ iwa ọdaran, State Criminal Investigation Department bẹrẹ iṣẹ iwadii naa ni kikun, lati le mọ ibi ti wọn ti ba ẹgbẹ buruku naa de.
Ogunlọwọ tun sọ pe oun fẹẹ foju kan gbogbo awọn ọmọ naa lọjọ Aje, oni lati fọrọ wa wọn lẹnu wo, ko to di pe wọn tare wọn si ọdọ awọn olugbaninimọran.
Bẹẹ lo gba obi, alagbatọ, olukọ, awọn olori agbegbe lati fọwọ sowọpọ lori bi wọn yoo ṣe gbogun ti iwa ẹgbẹ okunkun kaakiri ile-ẹkọ.
No comments:
Post a Comment