Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti kọminu lori awọn agba alẹnulọrọ meji ti wọn jade laye nipinlẹ Kwara.
Agba alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, Alaaji Musa Mayaki ati Alangua tiluu Adewole, Alaaji Hanafi Ologbin lawọn mejeeji ti wọn ki ile aye pe o digboṣe.
Nigba to n sọrọ ninu atẹjade ibanikẹdun ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita lọjọ keji, oṣu Kẹta ti a wa yii, gomina sọ pe adanu nla ni iku mejeeji naa jẹ lasiko yii.
O ni bi iku awọn mejeeji ṣe jẹ adanu nla fun ipinlẹ Kwara lapapọ, bẹẹ naa lo tun jẹ adanu foun gangan ati gbogbo ilu Ilorin jakejado.
Bakan naa lo ba Emir ilu Ilorin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari kẹdun, to si rọ awọn araalu lati mu ọkan le, pẹlu adura wi pe ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment