Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun ti fidi ileri rẹ mulẹ nipa itọju awọn ọmọde nipinlẹ naa, to si tun jẹ ko di mimọ pe ko si ọmọ kankan ti wọn yoo ta danu lasiko yii.
Ijọba sọ pe ọjọ iwaju orileede yii, paapaa ipinlẹ naa ni awọn ọmọ jẹ, idi pataki ree to fi sọ pe gbogbo iranwọ ti wọn ba nilo lawọn yoo pese.
Kọmiṣanna feto araalu, Ọnarebu Nnafatima Imam Mariam lo sọ eyi di mimọ l'Ọjọru, ọsẹ yii lasiko abẹwo si ile itọju awọn ọmọde to wa ni Amoyo ati ọgba awọn ọmọde to wa ni Pipeline niluu Ilorin.
Ọnarebu Mariam, nigba to n sọrọ, jẹ ko di mimọ pe ọrọ igbayegbadun awọn ọmọde jẹ ijọba logun pupọ, to fi mọ ohun to nii ṣe pẹlu irori ati ọpọlọ wọn.
O ni o ṣe pataki fawọn ọmọde lati jẹ mudunmudun eto ijọba awa-ara-wa, ati pe baba gbogbo ọmọde ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq jẹ, ti yoo si maa ṣe iranlọwọ to ba yẹ lati jẹ ki wọn gbe igbe aye irọrun.
No comments:
Post a Comment