Amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode, Kọmureedi Olayinka Fafoluyi tọpọ awọn eeyan mọ si Solace ti ṣe bẹbẹ, koda o kọja gudugudu meje ati yaya mẹfa.
Fafoluyi lo gba fọọmu idanwo aṣewọle sile ẹkọ giga, JAMB fawọn akẹkọọ ti wọn ṣẹṣẹ jade ile ẹkọ girama ni awọn wọọdu bii Ipetu, Rore, Aran-Orin to wa nijọba ibilẹ Irepodun.
Awọn ọba alaye agbegbe naa ni Solace ko awọn fọọmu JAMB naa ti ko din ni ọgbọn fun lati pin in sita, ti awọn ọba naa si ṣeleri pe awọn yoo pin in fawọn to yẹ.
Nigba to n sọ erongba rẹ fawọn ọba alaye naa, Solace jẹ ko di mimọ pe nigba ti yoo ba fi di ọdun 2026, ipinu oun ni lati pin fọọmu naa kaakiri wọọdu to wa nijọba ibilẹ Irepodun ni Kwara.
Bakan naa lo ṣalaye pe fọọmu toun pin naa ko nii ṣe pẹlu erongba oun fun ipo oṣelu, bi ko ṣe lati gunle iwa aanu ti baba oun ati awokọṣe oun, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gunle kaakiri
Ṣaaju asiko yii ni ile ẹkọ giga fasiti tiluu Ilorin, UNILORIN fi lẹta idupẹ ranṣẹ si Solace lori bo ṣe ran awọn akẹkọọ kan lọwọ lati san owo ile ẹkọ wọn
Yatọ si eyi, Solace ti ṣe oriṣiriṣi iranlọwọ fawọn araalu, paapaa awọn akẹkọọ nipa riran wọn lọ sile ẹkọ, to si n san owo ile ẹkọ wọn loorekoore.
Bakan naa ni Solace tun fi ẹbun owo, idajo miliọnu kan naira ta idile olukọ rẹ lasiko to wa nile ẹkọ fasiti, Ọmọwe Ibikunle Anibijuwon lọrẹ, ẹni to tubọ ṣagbatẹru irin ajo ate rẹ nipa adura ati amọran.
No comments:
Post a Comment