Portable wọ Ọlamide nilẹ nita gbangba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 5, 2025

Portable wọ Ọlamide nilẹ nita gbangba


Gbajugbaja onkọrin takasufee nni, Habeeb Okikiola, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Portable, lo tun ti fẹsun kan ogbontarigi olorin takasufee nni, Olamide lori ẹsun wi pe o gba puromota rẹ.
 
Portable lo n sọrọ sita lẹyin awuyewuye aawọ to wa laaarin ilu mọn-ọn-ka olorin takasufee to wa pẹlu Ọlamide tẹlẹ Asake, to mu ko kuro.
 
Oriṣiriṣi awuyewuye lo ti n lọ kaakiri ori ayelujara wi pe aawọ wa laaarin Asake ati awọn alakoso ileeṣẹ YBNL to jẹ ti Olamide, leyi to mu ko kuro nibẹ.
 
Nigba to n sọrọ, Portable sọ pe niṣe ni Olamide kọ orin sinu orin oun, dibo ko fa oun wọle sinu ileeṣẹ awo orin rẹ, YBNL.
 
Portable sọ pe o tẹ Olamide lọrun bo ṣe kọ orin sinu orin oun, Zazu to si fun un ni iwuri ju Asake to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹyin rẹ nileeṣẹ naa.
 
Siwaju sii ni Portable tun fi kun un pe Olamide ja purodusa ati alajota oun gba, dipo ko gba oun wọle sinu ileeṣẹ rẹ.
 
Ninu ọrọ Portable, o sọ pe “Olamide Baddo, ti o ba ti sọ pe ki n maa bọ lati darapọ mọ ileeṣẹ awo orin rẹ, tidunnu-tidunnu ni maa fi gba lati wọle. Ṣugbọn dipo ki o gba mi wọle, niṣe lo ja purodusa mi, alajota ati olupolongo mi, Kogbaigidi lọwọ mi.
 
“Ẹni [Asake] ti o ran lọwọ ko ran ẹ niṣẹ mọ. Saa kan pere lo kọ ninu orin mi, to si n jẹ iwuri fun mi ju Aṣakẹ to ko gbogbo aye rẹ lẹ ọ lọwọ lọ. Wa a gbe mi larugẹ bi o ṣe gbe Aṣakẹ larugẹ, ki o wa woran boya nko ni mọ oore ju Asake lọ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI