Kwara: TESCOM kéde àyípadà nínú ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 26, 2025

Kwara: TESCOM kéde àyípadà nínú ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò


Ajọ to n ṣagbatẹru eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State Teaching Service Commission (TESCOM) ti kede awọn ayipada to waye ninu ilana eto ifọrọwanilẹnuwo to n lọ lọwọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni ajọ TESCOM ṣagbekalẹ eto idanwo fun gbogbo awọn ti wọn forukọsilẹ silẹ fun iṣẹ olukọ kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa.

Ṣugbọn ṣa, TESCOM sọ pe awọn ti fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si gbogbo awọn to yege fun ipele ifọrọwanilẹnuwo lati mọ boya wọn yoo yege fun iṣẹ naa.

Ninu atẹjade ti TESCOM gbe kade sita lọjọ Iṣẹgun ana, wọn jẹ ko di mimọ pe ayipada rampẹ ti wa ninu ibi awọn akopa yoo ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo wọn.

Ọjọ Iṣẹgun naa ni eto ifọrọwanilẹnuwo ọhun bẹrẹ lẹkunrẹrẹ fun awọn akopa nijọba ibilẹ Asa, Ilorin East, Ilorin South, ati Oke Ero. 

Awọn akopa nijọba ibilẹ Baruteen, Edu, Patigi, Kaiama, Irẹpọdun ati Iṣin ni yoo ṣe ni ọjọ keji tii ṣe oni, ti a si gbọ pe awọn 1,722 ni wọn n reti.

Akopa 1,384 ni wọn n reti fun ọjọ kẹta tii ṣe Tọside lawọn ijọba ibilẹ bii Ifẹlodun, Moro, Ọffa, Ekiti ati Oyun.

Bakan naa ni wọn n reti awọn akopa 1,310 lawọn ijọba ibilẹ Ilorin West ati 362 ti kii ṣe ọmọ ipinlẹ Kwara fun ọjọ kẹrin.

Gbọngan KWASU International Conference Centre to wa ninu ọgba fasiti ipinlẹ naa ni eto ifọrọwanilẹnuwo ọhun yoo ti waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI