Kii ṣe iroyin tuntun pe adiẹ dun lẹnu pupọ, paapaa awọn adiẹ oyinbo to yatọ si ti ibilẹ to pọ kaakiri.
Ọpọ ni kii fẹ danu duro bi wọn ba n jẹ adiẹ oyinbo lẹnu, bẹẹ si ree, adiẹ oyinbo pe oriṣiriṣi, lara rẹ si ni eyi ti wọn n pe ni Broiler wa.
Ki ni idi ti o ṣe gbọdọ ṣe ọsin adiẹ 'Broiler'?
• Awọn adiẹ Broiler maa n tete dagba, ti wọn si maa n tobi, ti wọn si maa n tete mu owo wọle.
• Ẹran adiẹ Broiler kii dilẹ lori igba, o jẹ ohun ti awọn eeyan n beere fun ni gbogbo igba, to si jẹ okoowo ti ko le kuta.
• Bibẹrẹ okoowo ọsin adiẹ Broiler ko gba ọpọlọpọ owo lati fi bẹrẹ bii awọn ohun ọsin yooku.
• Loorekoore ni owo n wọle fun agbẹ to ba yan ọsin adiẹ Broiler laayo, owo naa yoo maa wọle lai pariwo.
• Ko si ibi ti o ko ti le bẹrẹ ọsin adiẹ Broiler naa, yala lẹyinkule ile tabi ibi yoowu ti aye ba wa. Eyi lo si maa n sọ awọn eeyan di agbẹ keekeekee.
• Adiẹ Broiler ko lani loogun lati sin, tabi tọju, imọ diẹ lo nilo lati ni, ko to di pe o bẹrẹ.
• O le ta adiẹ Broiler laaye tabi lẹyin ti o ba pa a tan, eyi ti yoo jẹ ki owo wọle sapo rẹ.
• Igbẹ adiẹ Broiler tun n ṣiṣẹ gẹgẹ bi ajilẹ, to si n mu adinku ba idọti, to si tun n ṣagbelarugẹ fun eto ipawo-wọle.
• Bi o ba n ṣe ọsin adiẹ Broiler, ko si iṣẹ ti o ko tun le ṣe, o si tun le mu iṣẹ agbẹ bii ọgbin mọ-ọn leyi ti yoo fun ọ laaye lati tan iṣẹ agbẹ naa ka.
Ko pẹ ju bi o ba tete bẹrẹ ọsin adiẹ Broiler lonii.
No comments:
Post a Comment