Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti ọrọ naa yoo pada yọri si, pẹlu bi gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun ṣe fẹẹ lu ilẹ awọn Ẹgba ta ni gbajo, ṣugbọn t'awọn oloye sọ pe ala ti ko le ṣẹ ni.
Ilẹ to wa ninu ọgba ile ẹkọ ti iṣẹ ọwọ ti a mọ si Technical College to wa lagbegbe Idi-Aba niluu Abẹokuta ni iroyin fi to wa leti pe Gomina Dapọ Abiọdun ti bẹrẹ igbesẹ lati ta fawọn ajoji, eyi ti wọn ni ko tẹ awọn Ẹgba lọrun.
Ninu atẹjade ti igbimọ awọn oloye Ẹgba gbe jade laipẹ yii, ni wọn ti ṣe ikilọ fun gomina lati ma ṣe tẹsiwaju lori erongba lati ta ilẹ naa fun awọn ileeṣẹ aladani lati fi kọ ile.
Igbimọ awọn oloye Ẹgba sọ pe niṣe ni wọn ya ilẹ naa sọtọ fun eto ẹkọ lọjọ iwaju, kii ṣe lati fi kọ ile gbigbe, eyi ti gomina fẹẹ ṣe.
Wọn ni idunkooko ni igbesẹ ti Gomina Abiọdun fẹẹ gbe lodi si eto ẹkọ niluu Ẹgba.
Ninu lẹta naa ti igbimọ Ẹgba kọ ranṣẹ si Gomina Abiọdun, eyi ti awọn agba oloye bii Balogun Ẹgba, Oloye Sikirulai Atọbatẹlẹ; Lisa Ẹgba, Oloye Oluyọmi Ọlaogun ati Aro ilu Ẹgba, Oloye Oluyinka Kufilẹ buwọ lu, ni wọn ti fi ẹdun ọkan wọn han.
“O ti wa etiigbọ wa wi pe apa kan ninu ilẹ ile ẹkọ Tẹkinika ni wọn ti n la lati ta fun awọn eeyan aladani.
“Ilẹ yii la ya sọtọ fun eto ẹkọ lọjọ to ti pẹ, ṣaaju ko to di pe wọn da ipinlẹ Ogun silẹ, ati pe bi awọn ile-ẹkọ Tẹkinika ṣe n lo, ko gbọdọ jẹ eyi ti a maa gbabọdi fun,” lẹta naa ṣalaye.
Awọn oloye naa sọ pe oriṣiriṣi ẹgbẹ nilẹ Ẹgba bii 'Egba Economic Summit' ati 'Egba Think Tank' ni wọn ti fi sọrọ lori ilẹ naa to ti n di awuyewuye.
Ninu ijiroro ti wọn ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba, to fi mọ Kọmiṣanna fọrọ ile kikọ, fidi rẹ mulẹ pe wọn ti n mọ odi, iyẹn fẹnsi yi ọpọlọpọ ilẹ naa ka, lati fi ya ilẹ naa sọtọ pẹlu ile-ẹkọ.
Igbimọ awọn aṣaaju Ẹgba naa sọ pe kẹnikẹni ma ṣe gbiyanju lati fọwọ kan ilẹ Ẹgba, lati le daabo bo o fun ehun ti wọn fẹẹ fi ṣe lọjọ iwaju, iyẹn kikọ fasiti.
Wọn erongba ilẹ naa ni lati fi mu igbooro ba ile-ẹkọ naa, leyi ti wọn ni ipinnu lati kọ fasiti Tẹkinika lọjọ iwaju.
“A n fẹ ki ijọba dawọ igbesẹ wọn duro loju ẹsẹ, lati wa ilẹ miran ti wọn yoo lo, bi ilẹ ijọba to wa lẹyin ọgba mẹkaniiki to wa ni Ọbalende, eyi to fẹ lọ de ibudo oju-irin,” wọn sọ ninu lẹta naa.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe awọn ile akọku ati igbo kikun ti yoo wa ninu ọgba naa lẹ ṣakoba fun eto aabo, leyi ti yoo ko awọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ sinu ewu eto aabo.
Wọn ni ki gomina lo ipinnu 'Igbega ipinlẹ Ogun, ajọṣe gbogbo wa ni', lati fi mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba ipinnu ti wọn ni lati sọ ile-ẹkọ naa di fasiti.
Siwaju ni wọn ṣalaye pe bi ipinlẹ Ogun ṣe n tẹsiwaju nipa iṣẹ bii dida iṣẹ silẹ ati dida okoowo silẹ, ki gomina lo anfaani naa lati ṣagbelarugẹ ẹka eto ẹkọ ti Tẹkinika naa.
Titi dasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ko tii si atẹjade kankan lati ọdọ gomina tabi ileeṣẹ agbẹnusọ fun ijọba.
No comments:
Post a Comment