Ilana ipolowo ọja gbọna ara yọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 4, 2025

Ilana ipolowo ọja gbọna ara yọ ni Kwara


Lojuna lati mu idagbasoke ba agbelarugẹ awọn eto akanṣe iṣẹ idagbasoke laarin ilu, ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣagbekalẹ ilana tuntun tawọn araalu yoo maa gba polowo ọja wọn.
 
Ijọba ti wa gbe igbimọ agbofinro dide, ti yoo maa ri si bawọn ileeṣẹ to n polowo ọja yoo ṣe maa ri awọn irin ati patako alẹmode tawọn olokoowo n lo lati fi polowo ọja ati ileeṣẹ wọn.
 
Igbimọ naa lo sọ eyi di mimọ nibi ifilọlẹ wọn to waye ninu gbọngan ipade ti ileeṣẹ kọmiṣanna feto ikansira-ẹni, Ọnarebu Bolanle Olukoju, to wa niluu Ilorin.

Olukoju ṣalaye pe igbesẹ naa lo lọ nibamu pẹlu agbekalẹ lati mu itẹsiwaju ba Kwara lọna igbalode, ati eto aabo araalu, to fi mọ eyi ti yoo ba ilana ipolowo lagbaye mu.

Olukoju sọ pe igbimọ agbofinro naa yoo maa lọ lati ṣe atunṣe, lati rii pe awọn ileeṣẹ ipolowo n ri awọn alẹmode wọn nibamu pẹlu ilana tuntun kaakiri ilu Ilorin ati agbegbe rẹ, to fi mọ awọn ilu yooku nipinlẹ Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI