Ijọba Kwara dide ogun sawọn araalu lori iwa idọti ati aini imọtoto - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 4, 2025

Ijọba Kwara dide ogun sawọn araalu lori iwa idọti ati aini imọtoto


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe opin ti de ba gbogbo iwa aini imọtoto ati iwa idọti ti awọn araalu n hu kaakiri, ati pe ẹni tọwọ palaba rẹ ba ti segi yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ.
 
Adele ọga agba ileeṣẹ wolewole to n ṣobojuto eto imọtoto ayika ati agbegbe nipinlẹ Kwara, Kwara State Environmental Protection Agency (KWEPA), Hajia Idayat Folorunsho lo sọ eyi di mimọ niluu Ilọrin, lasiko ipolongo ti wọn ṣe kaakiri lati kede fun araalu lati tọwọ ọmọ wọn aṣọ nipa didọti aarin ilu.
 
Hajia Folorunsho jẹ ko di mimọ pe bi eto aabo ati ilera araalu ṣe jẹ ijọba ipinlẹ naa logun, awọn araalu naa nilo lati ran ijọba lọwọ nipa itọju ayika ati agbegbe wọn.

Nigba to n sọrọ, o sọ pe awọn ko nii gba iwa idọti laaye mọ nipinlẹ naa, ati pe ẹni tọwọ ba tẹ lasiko to n da idọti sawọn ibi ti ko yẹ, paapaa ẹgbẹ opopona yoo foju winna ofin.

Hajia Folorunsho, to lewaju awọn wolewole naa jade lọjọ Iṣẹgun to kọja sọ pe awọn oniṣọọbu to wa lawọn ẹgbẹ opopona kaakiri gbọdọ dẹkun dida idọju sawọn agbegbe ti omi n gba kọja, leyi ti yoo dẹkun omiyale, agbara ya ṣọọbu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI