Ijọba Kwara buwọ lu biliọnu marun-un naira lati fi ṣagbelarugẹ awọn ile iwosan alabọde - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 14, 2025

Ijọba Kwara buwọ lu biliọnu marun-un naira lati fi ṣagbelarugẹ awọn ile iwosan alabọde


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọ lu owo ti ko din ni biliọnu marun-un naira lati fi mu idagbasoke ba awọn ile iwosan alabọde kaakiri ipinlẹ naa, paapaa awọn eyi to fẹẹ dẹnukọlẹ tan, lati gbe wọn dide.
 
Igbesẹ yii ni gomina ṣe lati le jẹ ki gbogbo olugbe ipinlẹ naa, paapaa awọn to n gbe lawọn igberiko ipinlẹ naa ni anfaani si eto ilera igbalode ati alabọde.

Gẹgẹ bi atẹjade to wa lati ileeṣẹ to n ṣabojuto awọn ile iwosan alabọde niìnlẹ Kwara, Kwara State Primary Health Care Development Agency (KWHCDA), eyi ti akọwe agba, Ọjọgbọn Nusirat Elelu buwọ lu, o jẹ ko di mimọ pe ile iwosan alabọde ti ko din ni aadọrin ni yoo gba ayipada ọtun.
 
Ọjọgbọn Elelu sọ pe awọn ile iwosan alabọde naa ni yoo bọ si ipele keji.

Akọwe agba naa lo sọrọ yii nibi ipade to waye nileeṣẹ naa, eyi ti wọn fi buwọ lu igbesẹ naa. Lara rẹ si ni wọn yoo ti ra awọn irinṣẹ amuyẹ, atunṣe ile ati awọn nnkan miran, to fi mọ ṣiṣe ina to n lo oorun, iyẹn Solar, leyi ti yoo fopin si idakureku ina mọnamọna.
 
Awọn nnkan miran ti wọn yoo tun ṣe ni omi ẹrọ igbalode, kikọ ile fawọn oṣiṣẹ eleto ilera ti yoo maa ṣiṣẹ nibẹ, ati awọn anfaani miran to yẹ ile iwosan.

Ọjọgbọn Elelu jẹ ko di mimọ pe nipa iranlọwọ banki agbaye, eyi ti wọn fi n ṣatilẹyin fun abẹrẹ ajẹsara, labẹ eto ti wọn pe ni Immunisation Plus and Malaria Progress by Accelerating Progress and Transforming Services (IMPACT).”

O ni atunṣe naa yoo jẹ ki awọn ile iwosan alabọde naa wa ni ipo to yẹ ki wọn wa, ni ibamu pẹlu ilana ati agbekalẹ agbaye, fun araau lati le jẹ anfaani ilera ọtun lowo pọọku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI