Eyi lawọn meji ti Gomina AbdulRazaq forukọ wọn ranṣẹ sile igbimọ aṣofin fun ipo Kọmiṣanna - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 27, 2025

Eyi lawọn meji ti Gomina AbdulRazaq forukọ wọn ranṣẹ sile igbimọ aṣofin fun ipo Kọmiṣanna


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi orukọ awọn meji ranṣẹ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa fun ipo Kọmiṣanna.

Ọmọwe Lawal Olohungbebe ati Mariam Nnafatima Imam lawọn mejeeji ti gomina fẹẹ lo fun ipo Kọmiṣanna to fẹẹ ṣi silẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Olohungbebe ni amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto idagbasoke agbegbe, nigba ti Imam jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori Sustainable Development Goals (SDG).

Awọn mejeeji yii ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa yoo ṣagbeyẹwo wọn, lati mọ boya wọn kaju oṣuwọn fun ipo Kọmiṣanna, ko to di pe wọn fontẹ lu wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI