Efele di alaga fẹgbẹ awakọ RTEAN l'Ogun lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 26, 2025

Efele di alaga fẹgbẹ awakọ RTEAN l'Ogun lẹẹkeji


Orin 'Efele, maa ba iṣẹ rẹ lọ, iṣẹ rẹ maa n tẹ wa lọrun' lawọn ọmọ ẹgbẹ awakọ, ẹka ti Road Transport Employers Association of Nigeria (RTEAN), ẹka tipinlẹ Ogun n kọ nigba ti wọn tun dibo yan Alaaji Titlayọ Akibu tọpọ awọn eeyan mọ si Efele gẹgẹ bi alaga wọn fun igba keji.

Yatọ si Efele ti wọn dibo yan gẹgẹ bi alaga fun saa keji, wọn tun yan Tiwalade Akingbade gẹgẹ bi akọwe ẹgbẹ naa fun igba keji.

Ọdun marun-un gbako ni wọn yoo lo fun saa keji yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Eto idibo ọhun lo waye nile ẹgbẹ RTEAN lọjọ Aje, Mọnde to kọja yii, eyi ti aarẹ wọn lapapọ, Musa Maitakobi ati awọn alaṣẹ ṣakoso rẹ.

Nigba to n sọrọ, aarẹ ẹgbẹ naa, Musa Maitakobi tọka si awọn iṣẹ akikanju wọn lati ni ibaṣẹpọ to dan mọnran laaarin awọn ọmọ ẹgbẹ ati ajọ ẹṣọ oju popona, ẹka ti Federal Road Safety Corps (FRSC).

Maitakobi jẹ ko di mimọ pe lara awọn ohun to wa ninu adehun tawọn tọwọ bọ pẹlu FRSC ni lati ṣagbekalẹ ile-ẹkọ ọkọ wiwa nipinlẹ Ogun, leyi ti yoo fopin si aini imọ kikun laaarin awọn awakọ.

Bakan naa lo ṣeleri wi pe oun yoo ba awọn oloye ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun sọrọ lati ṣagbekalẹ ile-ẹkọ ọkọ wiwa silẹ l'Ogun.

Siwaju sii lo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati jawọ ninu iwa jagidijagan ati iwa ipa, eyi to n ba orukọ ẹgbẹ naa jẹ, ati pe ki wọn gbe iwa ọmọluabi wọ ni gbogbo igba lati le jẹ ki wọn da RTEAN yatọ si NURTW.

Akọwe ẹgbẹ naa, Tiwalade Akingbade gbe oṣuna kare fun alaga wọn, Titlayọ Akibu lori akitiyan ati ipa to ko ni saa akọkọ, to si ni aṣeyọri naa lo fa bi wọn ṣe dibo yan an lẹẹkeji.

Akingbade ṣleri pe saa keji yii yoo tayọ kọja saa akọkọ, pẹlu bo ṣe ni alaga yoo tẹsiwaju lori awọn aṣeyọri to dawọle.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI