Ẹ wo aworan bi ile-ẹjọ igbalode alaja mẹfa ti ijọba Kwara fẹẹ kọ yoo ṣe ri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 14, 2025

Ẹ wo aworan bi ile-ẹjọ igbalode alaja mẹfa ti ijọba Kwara fẹẹ kọ yoo ṣe ri


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, ti gbe aworan bi ile ẹjọ igbalode alaja mẹfa , eyi ti wọn pe ni 'Court House' sita fawọn araalu, lati mọ bi yoo ti ṣe ri.
 
'Court House naa ni wọn fẹẹ kọ sagbegbe Ahmadu Bello Way to wa niluu Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara, ti wọn si ti fi lọlẹ lọsẹ to kọja.

Ninu atẹjade ti Olayinka Fafoluyi to jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode fi sita, o jẹ ko di mimọ pe akọkọ iru rẹ ree nilẹ Afrika, nitori pe ko tii si iru rẹ rii.
 
Fafoluyi ni itan tuntun ni Gomina AbdulRazaq fẹẹ fi balẹ yii, ati pe ọga oun ti gbe iṣẹ naa fawọn alagbaṣe lati bẹrẹ iṣẹ.
 
Diẹ ree lara awọn aworan naa...





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI