Banki agbaye fun ipinlẹ Kwara ni aami ẹyẹ RAAMP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 3, 2025

Banki agbaye fun ipinlẹ Kwara ni aami ẹyẹ RAAMP


Ile ifowopamọ agbaye ti gbe awọọdu to jọju fun ipinlẹ Kwara lori bi wọn ṣe n ṣamulo owo iranwọ fawọn agbẹ, eyi ti yoo yọ wọn kuro ninu iṣẹ ati oṣi, ati agbelarugẹ ba eto ọrọ aje wọn.

Abẹ eto ti wọn pe ni Rural Access and Agricultural Marketing Project (RAAMP), eyi ti ile ifowopamọ agbaye n ṣagbatẹru ni wọn ti fi n ṣe iranwọ fawọn agbẹ.

Ọjọ Aje ana ni wọn gbe aami ẹyẹ idalọla naa fun ipinlẹ Kwara nibi akanṣe eto RAAMP, ẹlẹẹkẹjọ iru ẹ to waye niluu Abuja, olu-ilu Naijiria.

"Oriire nla leyi jẹ fun ipinlẹ wa. O si ṣafihan bi gomina ṣe fi ara jin fun iṣẹ idagbasoke. Awọọdu yii jẹ aridaju igbiyanju rẹ lati mu ilọsiwaju ba ipinlẹ wa," Kọmiṣanna feto iṣẹ ati igbokegbodo ọkọ, Onimọ-ẹrọ Abdulquawiy Olododo so eyi di mimọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI