Wẹrẹ ni iroyin iku Alaaji Isiaka Yusuf Okunrinjeje to jẹ Balogun Ajikobi tiluu Ilọrin nipinlẹ Kwara jade sita, to si n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi.
Bo tilẹ jẹ pe baba naa dagba ko too ki aye pe o digboṣe, sibẹ ko sẹni to fẹ ki baba naa ku, paapaa lori awọn ipa to ti ko ninu eto idagbasoke ilu Ilorin lapapọ.
Gomina Abdulrahman Abdulrazaq naa kọminu lori iku Balogun Ajikobi tiluu Ilorin ọhun, to si ni akikanju to ja fun idagbasoke alaafia ni oloogbe.
Oloogbe naa ni Balogun Ajikobi tiluu Ilorin kejila.
Gomina Abdulrazaq sọ pe "oloogbe naa to tun jẹ alẹnulọrọ ṣagbelarugẹ ẹwa, ohun ajogunba ati ọrọ ilu Ilorin ni gbogbo igba."
Bi gomina ṣe n ba ẹbi oloogbe naa kẹdun, bẹẹ naa lo n ba Emir ilu Ilorin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari, ati gbogbo ọmọ ilu Ilorin lapapọ kẹdun iku baba naa.
No comments:
Post a Comment