Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe ki gbogbo araalu nipinlẹ Ogun wa ni ikiyesara, pẹlu bi wọn ṣe l'awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto nipinlẹ naa ṣe fẹẹ kọju ija sira wọn.
Awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto, ẹka ti Ogun State Park Management (OGSPAM) la gbọ pe wọn fẹsun kan alaga ẹgbẹ onimọto ti, National Union of Road Transport Workers (NURTW), Alaaji Mustapha Yaro.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn ọmọ ẹgbẹ OGSPAM sọ pe Alaaji Yaro ti n gbero lati da wahala nla silẹ nipinlẹ Ogun lọjọ Aje, ọsẹ yii, iyẹn ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025.
Ẹsun yii ni wọn fi kan Alaaji Yaro pẹlu bi wọn ṣe n gbọ firinfirin wahala ti wọn lo fẹẹ ṣẹlẹ l'awọn agbegbe kan, lori bi wọn ṣe n sọ pe awọn kan fẹẹ fipa gba garaaji.
Awọn ọmọ ẹgbẹ OGSPAM naa ti Alaaji Abodunrin jẹ alaga wọn ninu ẹsun ti wọn fi kan Yaro, jẹ ko di mimọ pe ọkunrin naa to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo fẹẹ kọju ija s'awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto ti wọn jẹ ti APC.
Kii ṣe iroyin tuntun pe aawọ ti wa ninu ẹgbẹ onimọto naa tẹlẹ, ti aawọ ọhun si ti wa n di ti ọrọ oṣelu de bayii.
Wọn ni gbogbo ọna ni Yaro n wa lati kọju ija nla si awọn alatako rẹ laaarin ẹgbẹ naa.
Nigba to n sọrọ, Alaaji Abodunrin fi ẹdun ọkan rẹ han pe bi awọn agbofinro ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ, o ṣee ṣe ki wahala tawọn araalu ko lero dide.
Ninu ọrọ rẹ, Abodunrin sọ pe "Gbogbo awọn alakoso ileeṣẹ eleto aabo la n pe lati tete gbe igbesẹ to yẹ, ko too pẹ ju.
"Ọrọ oṣelu ti wọn fẹẹ mu ohun to n ṣẹlẹ yii le da wahala ti apa ko nii le tete ka silẹ nipinlẹ Ogun," Abodunrin jẹ ko di mimọ.
Bẹẹ ni wọn n pe fun ipade asọyepọ ati alaafia ti yoo jẹ ki ifẹ jọba laarin wọn, ki wọn si le jẹ ki ifọkanbalẹ wa laarin ilu.
Gbogbo akitiyan lati ba Alaaji Mustapha Yaro sọrọ lori ẹsun naa lo ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Ṣugbọn ṣa, pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto NURTW ṣe kọ lati sọrọ lori ẹsun yii lo n jẹ kayeefi ati ibẹru fun gbogbo araalu.
Fun awọn to ba mọ, ija to maa n waye laaarin awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto nipinlẹ Ogun kii waye nirọwọ irọsẹ.
Bi ẹmi awọn eeyan ṣe maa n lọ sii, naa ni dukia tun maa n bajẹ kọja sisọ, to si jẹ pe o maa n gba ọpọlọpọ oṣu ki apa ijọba to le ka a.
No comments:
Post a Comment