Ijọ Seventh-Day Adventist (SDA) to wa ni Wenchi West District ti Mid-West Ghana Conference, Bono Region, ti bu ọla ati ẹyẹ fun awọn ọmọdebinrin ti ko din ni ogun lori wi pe wọn ko tii ja ibale wọn.
Awọn ọmọdebinrin naa ni wọn wa laaarin ọdun mẹtala si mẹrindinlogun.
Ibi eto ayẹyẹ isin idupẹ to waye ninu ijọ naa laipẹ yii ni wọn ti bu ọla fun wọn pẹlu iranlọwọ owo nla.
Gẹgẹ bi iroyin GhanaWeb ṣe gbe e jade, ẹka kan ti wọn pe ni Young Adventist Women Ministries ninu ijọ naa la gbọ pe wọn ṣagbekalẹ eto naa, lati gbaruku ti iwa ọmọluabi, iyi ninu ẹsin Kristẹẹni ati aṣa wọn.
Alakoso Young Adventist Women Ministries, Arabinrin Nana Amponsah Poku, nigba to n ṣalaye idi pataki ti wọn fi ṣagbekalẹ eto ọhun, o ni o ṣe pataki lati mu aṣa lọkunkundun.
O tẹnumọ idi to fi ṣe pataki lati nigbagbọ ninu ara ẹni, ṣiṣẹ ipinnu ọlọgbọn, to si gba awọn ọmọbinrin lamọran lati pa ara wọn mọ, ati pe ki wọn ṣọra nigba ti wọn ba n yan ọrẹ lọdun 2025.
“Ọlọrun da a yin lara ọtọ nipa rirẹwa, ti ẹ ko si gbọdọ gba ẹnikẹni laaye lati tan yin jẹ, ki wọn si ja ibale yin titi ọjọ igbeyawo,” Poku sọ fawọn ọmọbinrin naa.
Aṣa atijọ ti Bragoro tabi Dipo jẹ eyi to ṣe pataki nipa didaabo “ibale awọn ọmọbinrin, ati pe didaabo bo awọn ọmọdebinrin lati loyun jẹ eyi to ṣe pataki ninu idagbasoke awọn ọmọdebinrin ati awọn obinrin,” o fi kun ọrọ rẹ.
Pasitọ Andrews Dua Bour Kyereh ti ijọ naa gbe oṣuba kare fun awọn ọmọdebinrin naa lori bi wọn ṣe ko ara wọn nijanu, ti wọn si pa ara wọn mọ.
O gba wọn niyanju lati gbajumọ eto ẹkọ ati igbagbọ wọn, to si rọ awọn ọmọdebinrin yooku ninu ijọ naa lati fi ti wọn ṣe arikọṣe.
Bakan naa ni Pasitọ Kyereh tun rọ awọn obi ati alagbatọ lati mu ọrọ gbigbajumọ awọn ọmọbinrin wọn lọkunkundun nipa gbigbe igbe aye to dara lai labawọn.
No comments:
Post a Comment