Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti ọrọ yiyan Alaafin Oyo tuntun yoo ja si, pẹlu bi rogbodiyan ṣe n fojoojumọ dide laaarin ijọba atawọn afọbajẹ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọrọ ipo naa tun gbọna miran yọ l’Ọjọbọ to kọja, nigba ti wọn sọ pe Gomina Makinde yan afọbajẹ tuntun meji dide, ṣugbọn ti wọn lawọn afọbajẹ faake kọri.
Ohun ti a gbọ pe awọn Afọbajẹ naa ti ṣe eto idibo lati yan ọmọ oye, ti wọn si ni ọkan lara awọn ọmọọba, Ọmọọba Lukman Gbadegesin lo jawe olubori.
Eyi ni wọn sọ pe ko dun mọ Gomina Seyi Makinde tipinlẹ naa ninu, ti wọn lo fi gbe awọn afọbajẹ meji dide, lati le jẹ ki wọn tun eto yiyan ọmọ oye naa ṣe, bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ.
Wọn ni awọn afọbajẹ marun-un naa sọ pe awọn ko le gba lati tun eto ati ilana naa ṣe.
Awọn afọbajẹ marun-un naa ni Baṣọrun ilu Oyo, Oloye Yusuf Akinade; Lagunna ilu Oyo, Oloye Wakeel Akindele; Akinniku ilu Oyo, Ọloye Hamzat Yusuf; ati oloye kan to n duro fun Aṣipa ilu Oyo, Oloye Wahab Oyetunji; to fi mọ oloye kan naa toun n duro fun Alapinni ilu Oyo, Oloye Gbadebo Mufutau.
Latigba ti Ọba Lamidi Adeyemi kẹta ti waja lọjọ kejelelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni wahala yiyan Alaafin tuntun ti bẹrẹ
Ọdun mejilelaadọta ni Ọba Adeyẹmi lo lori ipo naa, to si tẹri-gbaṣọ lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.
Ninu lẹta ti awọn afọbajẹ naa kọ ranṣẹ si Makinde, eyi ti agbẹjọro wọn, Adekunle Sobaloju buwọ lu, wọn ṣapejuwe igbesẹ gomina gẹgẹ bi eyi to tapa si ẹjọ to wa niwaju ile-ẹjọ nipa yiyan Alaafin Oyo tuntun.
No comments:
Post a Comment