Ajọ to n mojuto idanwo aṣekagba nilẹ ẹkọ girama, WAEC ti sọ pe anfaani tuntun ti wa fun gbogbo akẹkọọ ti wọn ba ṣakiyesi pe awọn ko ṣe daadaa ninu awọn iṣẹ kan pada tun iforukọsilẹ ṣe.
WAEC sọ pe eyi yoo fun awọn akẹkọọ naa lanfaani lati mu yege ninu gbogbo idanwo wọn, ko too pẹju, ati lati le wọ ile-ẹkọ giga lasiko.
Ajọ naa ni gbogbo akẹkọọ to ba ṣe idanwo naa to kọja, wọn ni anfaani lati tun idanwo naa ṣe lọdun 2025 ti a wa yii.
John Kapi to jẹ alakoso ilanilọyẹ lo sọrọ naa nileeṣẹ amohunmaworan ti ileeṣẹ JoyNews lorileede Ghana lọjọ Aiku to kọja.
Kapi sọ pe anfaani wa fawọn akẹkọọ lati tun idanwo naa ṣe laarin oṣu Kinni si oṣu Keji, ọdun yii.
“Awọn akẹkọọ ti wọn yẹ esi idanwo wọn wo, ti wọn si ṣakiyesi pe awọn nilo lati tun idanwo kan tabi meji ṣe ni anfaani lati ṣe iforukọsilẹ lori ikanni wọn titi di ọjọ kẹjọ, oṣu Kinni, tabi ki wọn lọ si eyikeyi ileeṣẹ Cyber Cafe ti wọn fun laṣẹ lagbegbe wọn lati forukọsilẹ.
“Idanwo naa yoo waye laaarin ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kinni, si ọjọ kẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun 2025,”Kapi ṣalaye.
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti wọn wọgile idanwo naa le tun ifọrukọsilẹ ṣe, niwọn igba ti wọn ko ba fi da wọn lọwọ kọ lori ẹsun magomago idanwọ.
No comments:
Post a Comment