Sẹnetọ Adeola Yayi tu aṣiri tuntun nipa bo ṣe pada sipinlẹ Ogun lati gbegba oṣelu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 4, 2025

Sẹnetọ Adeola Yayi tu aṣiri tuntun nipa bo ṣe pada sipinlẹ Ogun lati gbegba oṣelu


...Ọba Olugbenle lọ bẹrẹ irin ajo ti mo fi pada sipinlẹ Ogun lati gbegba oṣelu – Yayi

Sẹnetọ Solomon Olamilekan Adeola tọpọ awọn eeyan mọ si Yayi ti sọ ọ nita gbangba wi pe olori ọba ilẹ Yewa lapapọ, Ọba Kehinde Olugbenle lo jẹ koun bẹrẹ irin ajo lati wa gbegba oṣelu nipinlẹ Ogun.

Sẹnetọ Yayi lo sọrọ naa lasiko to n ṣe idupẹ nibi akanṣe eto isin idupẹ to gbe kalẹ niluu Ilaro loni ọjọ Abamẹta, Satide.

Inu ijọ Ridiimu ti Unity Cathedral, Ogun Province 7 to wa niluu Ilaro Yewa ni eto isin idupẹ naa ti waye.

Nigba to n sọrọ, Yayi sọ pe; 
“Lẹẹkan si, mo fẹẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun iru ọjọ bayii. Mo fẹẹ dupẹ lọwọ awọn pasitọ wa fun bi wọn ṣe wa sibi lonii, lati ṣagbatẹru wa ninu isin idupoẹ yii.

“Mo tun dupẹ lọwọ awọn akọrin ti wọn fi orin da wa laraya. Mo tun dupẹ lọwọ Ọba alaye ilẹ Yewa, Ọba Olugbenle, Aṣade Agunloye.

“Nigba ti mo n sọ ẹri mi, iorin ajo lati pada si ibi ti mo ti wa bẹrẹ lati ọdọ Kabiyesi, Kabiyesi ni wọn gba mi lamọran lati pada wa sile, mo si dupẹ pe gbogbo rẹ ti n ṣe daadaa.

“Ohun ti ọpọ eeyan ni mi ko mọ ni pe Gomina Dapọ Abiọdun lo lọ sọdọ Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu, Aarẹ Naijiria, o si sọ fun aarẹ pe Yayi fẹẹ pada sile.

“Aṣiwaju sọ pe igbakẹta ti Yayi ti n gbiyanju lati pada sile o, ati pe ṣe gomina ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu Yayi lati pada sile, gomina si loun ti ṣetan.

“Bayii ni gbogbo irin ajo naa ṣe bẹrẹ, lẹẹkan si, mo fẹẹ dupẹ lọwọ Gomina Dapo Abiodun Oluwaseun fun atilẹyin rẹ lori bi mo ṣe pada sipinlẹ Ogun lati gbegba oṣelu.

“Mo tun dupẹ lọwọ Baba mi, Olusegun Osoba tpẹlu awọn amọran wọn, ipa ti wọn n ko ko kere rara.

“Gbogbo yin lẹ mọ pe ọmọ aarẹ wa ni Naijiria, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni mi, mo fẹẹ dupẹ lọwọ wọn pe bi wọn ṣe mu mi jade ninu oṣelu, ti wọn si n ṣe baba fun mi latigba ti baba mi ti ku, titi de ibi ti mo wa lonii. A ṣẹṣẹ bẹrẹ ayẹyẹ yii ni, pẹlu wẹjẹwẹmu.”

Bakan naa ni Sẹnetọ Yayi tun fi aadọta miliọnu naira ta ijọ Ridiimu ti isin idupẹ naa ti waye lọrẹ, lati fi ran iṣẹ akanṣe to n lọ lọwọ nibẹ lọwọ.

“Ni ana, mo ni anfaani lati wa sinu ijọ yii to jẹ olu-iya ijọ Ridiimu niluu Ilaro, mo lọ kaakiri pẹlu awọn Pasitọ, mo si ri bi iṣẹ ṣe n lọ, pẹlu bi ijọ naa ko ṣe tobi to, ẹ jẹ ki ohun gbogbo lọ nirọrun fun mi, mo dupẹ lọwọ yin.

“Mo ri iṣẹ akanṣe to n lọ, mo si fẹẹ nigbagbọ pe okoowo nla teeyan le ṣe ni lati ba Ọlọrun dokoowo papọ, ẹ ko le fi owo ba Ọlọrun dokoowo, ki ẹ si padanu, ko ṣee ṣe.

“Fun idi eyi lemi naa ṣe fẹẹ fi owo kekere temi silẹ fun itẹsiwaju kikọ ijọ yii, mo maa fi aadọta miliọnu naira silẹ fun kikọ ijọ yii siwaju sii.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI