Oludije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, AAC, Omoyele Sowore ti sọ pe awọn akẹgbẹ rẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Atiku Abubakar ati ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi kii ṣe ọmọ Naijiria.
Sowore sọ pe ọmọ ilẹ Cameroon ni Atiku Abubakar kii ṣe ọmọ Naijiria, bẹẹ si ni Peter Obi jẹ ọmọ ilẹ Biafra.
Ọkunrin naa lo sọrọ yii lori eto ori ayelujara Youtube ti wọn pe ni ‘Curiosity Made Me Ask’, eyi to farahan laipẹ yii.
Nigba to n sọrọ lori bo ṣe padanu ninu eto idibo to kọja, ati erongba rẹ boya yoo ṣi tun jade lọdun 2027, ọkunrin naa sọ pe ipadanu oun kii ṣe opin.
“Gbogbo awọn to dije du ipo aarẹ lọdun 2023 lo ku diẹ ki wọn jawe olubori lati di aarẹ, yatọ si ọkunrin ti wọn kede wi pe wọn yan; Tinubu. Nitori pe gbogbo awa ti a ko bori lati pads si ohun ti a n ṣe tẹlẹ; aanu ṣiṣe
“Nko ro pe ka gbe eto kalẹ yoo ṣiṣẹ fun wa. Nitori pe bawo ni oye ohun ti Atiku n sọ yoo ṣe ye awọn eeyan, nitori pe kii sọ Oyinbo.
“Ọmọ ilẹ Cameroon ni. Awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni ki ẹ beere lọwọ ẹ. Wọn sọ fun un wi pe ko yẹ ko jẹ aṣoju ẹgbẹ fun ipo aarẹ, nitori ti wọn rii pe ọmọ Cameroon ni.
“Ati ẹnikan yooku ti o darukọ, Obi, ọmọ Biafra loun naa. Fun idi eyi, bawo ni yoo ṣe ṣee ṣe lati jọ farahan lori eto kan naa? Ati pe Kamala Harris ko mọ iyatọ laaarin Naijiria ati Afrika, bawo la ṣe wa fẹẹ jẹ ọmọ ẹyin rẹ?”
No comments:
Post a Comment