Oṣiṣẹ EFCC mẹwaa dero atimọle lori ẹsun ole jija - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 9, 2025

Oṣiṣẹ EFCC mẹwaa dero atimọle lori ẹsun ole jija


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ oṣiṣẹ wọn mẹwaa lori ẹsun ole jija.

EFCC sọ pe awọn dukia kan lo poora, ti wọn si ni o ṣee ṣe ki awọn mẹwaa naa mọ nipa rẹ, idi ree ti wọn fi ti wọn mọle lati ṣewadii.

Ọjọru, ọsẹ yii ni ajọ EFCC jẹ ko di mimọ ninu atẹjade ti wọn fi sita.

Wọn ni awọn irinṣẹ kan to wa ni ikawọ awọn mẹwaa naa lo deedee poora, ti wọn ko si le sọ bawọn dukia naa ṣe rin in.

Ọsẹ to kọja ni EFCC sọ pe ọwọ tẹ awọn mẹwaa naa ti wọn n ṣiṣẹ lẹkun ileeṣẹ wọn to wa niluu Eko.

Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe abajade ti awọn oluṣewadii ileeṣẹ wọn ba ṣe, ni yoo fi han nipa iru igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe lori ẹsun naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI