Ẹgbẹ awọn ọdọ kan nipinlẹ Kwara, ti wọn pe ni Kwara Youths Development Advocacy Vanguard (KYDAV) ti rọ aarẹ tẹlẹ nile igbimọ aṣofin agba lorileede Naijiria, Sẹnetọ Bukola Saraki ati Sẹnetọ Salihu Mustapha lati dẹkun dida aafin Emir ilu Ilorin ru.
Wọn ni gbogob iwa madaru ti awọn agba oloṣelu mejeeji naa n da silẹ ninu aafin Emir ilu Ilorin ko ṣẹyin eto idibo gomina to n bọ lọdun 2027, ti wọn si ni ko tii to asiko.
Ẹgbẹ naa sọ pe gbogbo apilẹkọ ti Sẹnetọ to ti figba kan ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Kwara naa n ṣagbatẹru rẹ lodi si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo ku diẹ kaato.
Ninu atẹjade ti Ọmọwe Idris Bolakale to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Aje, ọsẹ yii, o ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ apilẹkọ naa wi pe Gomina AbdulRazaq korira Emir ilu Ilorin, Ọmọwe Ibrahim Kolapo Sulu-Gambari kii ṣe otitọ, bi ko ọgbọn lati da họwuhọwu silẹ lasan ni.
O ni ọna lati da ija ati iyapa silẹ laarin gomina ati Emir lasan ni apilẹkọ naa, eyi ti wọn ṣagbatẹru rẹ lati gbe jade.
Ẹgbẹ naa sọ pe igbesẹ kan ṣoṣo yii ni Saraki lo lasiko eto idibo gomina ipinlẹ naa lọdun 2003, nigba to fi tako Gomina Muhammad Alabi Lawal to ti doloogbe bayii.
Gbogbo akitiyan lati ba awọn agbẹnusọ Sẹnetọ Bukola Saraki ati Sẹnetọ Salihu Mustapha sọrọ lo ja si pabo titi digba ti a fi pari akojọpọ iroyin yii.
No comments:
Post a Comment