Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ti ayẹyẹ iwuye gbajugbaja akọroyin ati ogbontarigi sọrọsọrọ nni, Arabinrin Olaide Aderonke Ayinke Gold, tọpọ awọn olulufẹ rẹ mọ si Laide Gold gẹgẹ bi Iya Iroyin fun gbogbo ilu Meiran nipinlẹ Eko.
Onimeiran tiluu Meiran, Ọba Awoyemi Adisa Oroja la gbọ pe o fi oye tuntun naa da Laide Gold lọla, nitori awọn ipa rere to n ko lori eto iroyin.
AWIKONKO gbọ pe inu aafin Onimeiran to wa lopopona Meiran, ipinlẹ Eko ni eto iwuye ọhun yoo ti waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2025 ti a wa yii.
Agogo mẹsan owurọ ni eto ọhun yoo bẹrẹ ni pẹrẹu, pẹlu oniruuru alakalẹ eto fọjọ naa.
Wẹjẹwẹmu ko nii gbẹyin lọjọ naa, bẹẹ lawọn olorin to gbajumọ daadaa lagbaye ṣe ti ṣetan lati dalu bolẹ lọjọ naa.
Odu ni Laide Gold lagboole sọrọsọrọ nipinlẹ Eko ati agbegbe rẹ, kii ṣaimọ foloko, bẹẹ naa lo tun gbajumọ daadaa lagboole akọroyin nipinlẹ Eko.
Bi Laide Gold ṣe n sọrọ lori redio Bond FM, naa lo tun n kọ iroyin fun iwe iroyin Gbelegbọ ti ileeṣẹ The Nation n gbe jade lọsẹ-ọsẹ.
No comments:
Post a Comment