Gbogbo eto lo ti pari fun olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Oludaisi Olumide Elemide lati ba gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa sọrọ.
Ọnarebu Elemide ni yoo maa sọrọ lori afojusun ile igbimọ aṣofin fun ọdun 2025 nipinlẹ naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ori eto Oju Awo to n waye nileeṣẹ redio Fresh 107.98FM to wa niluu Abeokuta ni gbajugbaja ọnarebu naa yoo ti bawọn araalu sọ awọn aṣofin fun ọdun tuntun yii.
Yatọ si eyi, Ọnarebu Elemide yoo tun sọrọ nipa igbesi aye rẹ lati kekere, titi to fi wọnu ipo oṣelu, ati awọn iṣẹ to yan laayo fawọn eeyan.
Ọdun to kọja ni Ọnarebu Elemide to n ṣoju ẹkun Odeda nipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin di olori ile, lẹyin ti wọn dibo le olori ile igbimọ aṣofin naa tẹlẹ, Ọnarebu Oluomo toun n ṣoju agbegbe Ifo danu.
Ilu-mọn-ọn-ka sọrọsọrọ, Akinyemi Olatoye tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Alawiye Federation ni yoo ṣe atọkun eto ọhun, bẹrẹ lati agogo marun-un si meje irọlẹ oni, ọjọ Iṣẹgun, Tuside.
No comments:
Post a Comment