Ọba Jelili Olaiye, Ajeniju ti agbegbe Halleluyah nipinlẹ Osun ti sọ pe ọlọpaa mejidinlogun lo wa nibi ti awọn tọọgi ti lu oun lalubami ninu aafin oun lọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja.
Kabiyesi naa sọ pe yatọ si oun ti awọn tọọgi ọhun lu, o ni wọn tun lu awọn mẹrin miran kọja sisọ, to si lawọn farapa yannayanna.
Bakan naa ni Ọba Olaiya tun jẹ ko di mimọ pe awọn tọọgi ọhun ba dukia jẹ ninu aafin oun lasiko ikọlu naa.
Ọba Olaiya lo sọ eyi lasiko to n fi omije ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn akọroyin laipẹ yii, to si loun ṣi wa lori bẹẹdi toun ti n gba itọju nileewosan.
Kabiyesi naa ni ọlọpaa mejidinlogun, awọn ẹṣọ aabo Sifu Difẹnsi ni wọn wa ninu aafin oun lasiko ti awọn tọọgi naa de, ti wọn si lu oun, iyawo oun ati awọn meji miran.
O ni ẹsun ti wọn fi kan oun ni pe oun yan Imaamu fun agbegbe Ido Osun, to si loun ko mọ nnkankan nipa rẹ, nitori pe agbegbe Hallelujah loun jọba le lori.
Kabiyesi ni ko ṣee ṣe foun lati yan Imaamu si ilu toun ko ni aṣẹ nibẹ, ati pe oun ko tun le yan Imaamu nigba toun ko tii kọ mọṣalaṣi kankan.
“Ibi ti Ajeniju yan Imaamu si kii ṣe lori ilẹ Ido Osun. Iwa aafin mi ni mọṣalaṣi naa wa. Nko yan Imaamu lori ilẹ Ido-Osun. Iwaju aafin mi ni eto yiyan Imaamu naa ti waye, nibi ti a ti lọ kirun lọjọ naa,” Kabiyesi ṣalaye.
“Imaamu ti a ṣẹṣẹ yan yii lo pe irun Jumaati fun wa lọjọ Fraide to kọja lọhun. Igba ti a n palẹmọ lati kirun Jumaati to kọja yii ni awọn tọọgi ọhun de. Lọjọ naa, awọn agbofinro kan de sinu aafin mi ko to di pe awọn tọọgi ọhun de.
“Awọn agbofinro naa sọ pe ọga awọn ni ẹkun Ido-Osun lo ran wọn wa. Ko si pe ni ọga wọn, DPO naa de, to si sọ fun mi pe oun n gbọ awuyewuye wi pe mo yan Imaamu, mo si tun kọ mọṣalaṣi tuntun.
“Mo sọ fun un pe nko kọ mọṣalaṣi tuntun, ati pe iwaju aafin mi la ti kirun Jimọ. O ni Imaamu agba Ido-Osun lo fi ẹjọ sun pe o yẹ ka wa gba aṣẹ lọwọ oun, mo si sọ fun DPO pe nko yan Imaamu lori ilẹ Ido-Osun.
“Awọn ọlọpaa wa nibẹ lasiko ti wọn kọlu wa. Ẹkun Ido-Osun ati ẹka to n ri sọrọ ijinigbe lawọn ọlọpaa naa ti wa, to fi mọ awọn Sifu Difẹnsi ti gbogbo wọn jẹ mejidinlogun.”
Kabiyesi naa wa pe fun eto aabo to pe ye lati le dẹkun dida alaafia agbegbe naa ru, ati lati fun ijọba laaye lati ṣe iwadii kikun, ki wọn si le wa ọna abayọ si ohun to n fa wahala.
“Emi nikan kọ lawọn tọọgi naa ṣe ikọlu si. Iyawo mi, ọkan lara awọn oloye mi, Mayowa George, ati ọkan lara awọn agba aafa ti wọn n pe ni Aafa Agba ni wọn farapa yannayanna,” Kabiyesi jẹ ko di mimọ.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ati Sifu Difẹnsi ko tii sọ ohunkohun lori ikọlu ọhun.
No comments:
Post a Comment